Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ti sọ pe oludije s'ipo Aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmẹd Tinubu ti wa niluu Ilaro, ipinlẹ Ogun.
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le f'idi ohun ti Tinubu lọ nibẹ mulẹ lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, sibẹ, a gbọ pe nipaṣẹ oludije s'ipo aṣofin agba l'ẹkun Yewa, Sẹneto Ọlamilekan Adeọla lo fi lọ sibẹ.
Bẹẹ la tun gbọ pe Sẹnetọ Adeọla mu Tinubu lọ ba awọn agbaagba ilẹ Yewa lori eto idibo to n bọ lọna yii.
Ẹkunrẹrẹ iroyin naa n bọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment