Gbajugbaja Pasitọ kan to fi ilu Oyinbo ṣebugbe ni iroyin ti fi to wa leti wi pe o ti fun agba oṣere tiata nni, Ojo Arowoṣafẹ ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Fadeyi Oloro ni owo ti ko din ni miliọnu mẹta naira.
Pasitọ Tobi Adegboyega lorukọ pasitọ naa, oun lo si ni ṣọọṣi Salvation Proclaimers Anointed Church, ti awọn eeyan tun n pe ni SPAC Nation lo fun Fadeyi Oloro ni ẹbun owo pataki naa, pẹlu erongba lati fi tọju ara rẹ.
O loun fẹ ki agba oṣere naa to ti dẹrin pẹẹkẹ wọn lati kekere fi owo ọhun tọju ara rẹ, ko si wa ni alaafia to tọ.
Eyi ni wọn lo waye lẹyin ti Fadeyi Oloro rawọ ẹbẹ sawọn ẹlẹyinju aanu, paapaa ọmọ Naijiria fun iranlọwọ owo ti yoo fi tọju ara rẹ, ko ma ba a ku sinu aisan to kọ luu.
Ori eto kan ti agba sọrọsọrọ oloyinbo nni, Daddy Freeze maa n ṣe lori ikanni ayelujara ti Instagiraamu ni Fadeyi Oloro ti bẹbẹ naa l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii.
Nigba to n sọ idi pataki to fi fun Fadeyi Oloro ni owo naa, Pasitọ naa sọ pe
“Mo mọ Fadeyi Oloro daadaa. Mo ṣi wa ni kekere, nigba ti a maa n wo Baba Fadeyi Oloro. Ọkan pataki lara awọn akọni ti a ni nilẹ Afrika ni baba naa jẹ.”
Bẹẹ lo tun fi da Fadeyi Oloro loju pe yatọ si owo naa, oun yoo tun maa gbe bukata rẹ, titi ti ara rẹ yoo fi ya patapata.
No comments:
Post a Comment