Gbajumọ oṣere tiata wọ gau nitori owo naira tuntun to ṣe baṣubaṣu lode ariya - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 3, 2023

Gbajumọ oṣere tiata wọ gau nitori owo naira tuntun to ṣe baṣubaṣu lode ariya


Ika abamọ ni gbajugba oṣere tiata nni, Oluwadarasimi Ọmọṣẹyin mu sẹnu nigba tọwọ ajọ to n gbogun iwa ajẹbanu ati ṣiṣẹ owo kumọkumọ lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka t'ipinlẹ Ekoo tẹ ẹ.
 
Ẹsun wi pe o n ṣe owo naira tuntun to ṣẹṣẹ jade sita, eyi ti ko tii kari gbogbo araalu kumọkumọ lode ariya kan to waye laipẹ yii nipinlẹ Eko.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ẹsun ti wọn fi kan Oluwadarasimi  lo tako abala kọkalelogun, idi karun-un (Section 21 (5)) ninu iwe ofin banki apapọ orileede Naijiria, Central Bank of Nigeria, CBN ti ọdun 2007.

Ninu atẹjade ti ajọ EFCC gbe jade lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun ti a wa yii, wọn ni ajọ ICPC, iyẹn Independent Corrupt Practices and Other Fraud Related Offences Commission, lo rọwọ to obinrin naa lọjọ kinni, oṣu keji, ọdun yii lagbegbe Awolọwọ, Ikoyi, l'Ekoo.
 
Wọn sọ siwaju pe iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lori ibi ti gbajugbaja oṣerebinrin naa ti ri owo to n ṣe baṣubaṣu.
 
F'awọn ti ko ba mọ, laipẹ yii ni fọnran kan jade sori ikanni ayelujara, nibi ti obinrin naa ti n na owo naira tuntun ninakuna lode ariya, to si tun n tẹ owo tuntun naa mọlẹ, bi ẹni pe oun lo ṣe e, eyi ti ọpọ awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI