Ẹni to ba ṣe iwọde ifẹhonuhan lasiko yii yoo jẹ iyan rẹ n'iṣu - Ọlọpaa Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 9, 2023

Ẹni to ba ṣe iwọde ifẹhonuhan lasiko yii yoo jẹ iyan rẹ n'iṣu - Ọlọpaa Kwara


Ileeṣẹ ọlọpaa n'ipinlẹ Kwara ti kede sita wi pe ko gbọdọ si iwọde ifẹhonuhan kankan lasiko yii n'ipinlẹ naa, ati pe ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ to ba gbiyanju ẹ yoo foju winna ofin.
 
Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe atẹjade naa sita wi pe alaafia ati aabo ẹmi ati dukia awọn araalu lo jẹ wọn logun.

Gẹgẹ bi ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Paul Odama, ṣe ṣalaye ninu atẹjade ọhun,  o ni ọpọ awọn ọdaran ni wọn n wa ọna ti wọn yoo fi da wahala silẹ laarin ilu, ti wọn si maa n lo anfaani ifẹhonuhan alalaafia lati ṣiṣẹ buruku wọn.
 
O loun ko le laju silẹ mọ lati jẹ k'awọn ọdaran maa ba dukia awọn araalu jẹ lai ni idi kan ni pato, ti wọn si lawọn ko le gba iru iwa bẹẹ laaye mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI