Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, l'Ọjọru, Wẹsidee oni ti tu aṣiri nla nipa awọn Kabaa to sọ pe wọn n ṣiṣẹ lodi si Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu lati di aarẹ orileede Naijiria lọdun 2023 ti a wa yii.
O ni gbogbo ọna ni awọn Kabaa naa n wa lati rii pe oludije s'ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ko jawe olubori, to si ni wọn n dunkooko mọ erongba rẹ lati di aarẹ.
El-Rufai lo tu aṣiri naa lori amohunmaworan ileeṣẹ Channels, lori eto Sunrise Daily.
O ni
“Mo mọ pe awọn kan wa ni ile agbara, iyẹn Villa lati rii pe a padanu eto idibo to n bọ yii, nitori pe wọn ko ri ọna wọn; wọn ni oludije ti wọn. Oludije wọn ko si bori ninu eto idibo abẹle.”
O tẹsiwaju pe awọn oludije wọn ti padanu lakoko eto idibo abẹle ti ẹgbẹ wọn ṣe.
“Wọn n fẹ ka padanu eto idibo yii, wọn n sa si abẹ ipinnu aarẹ lati ṣe ohun ti wọn ro pe o tọ. Maa fun un yin ni apẹẹrẹ meji; ọrọ owo ori epo rọbii, eyi ti wọn n na obitibiti owo le lori, eyi si ni gbogbo wa sọ pe ki wọn yọ kuro...”
No comments:
Post a Comment