Ẹ wo bi awọn olufẹhonuhan ṣe ba awọn banki jẹ ni Ṣagamu (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 21, 2023

Ẹ wo bi awọn olufẹhonuhan ṣe ba awọn banki jẹ ni Ṣagamu (Fọto)


Nisẹ lọrọ di boolọ o yago lọna l'ọjọ Aje, Mọnde ana nigba ti wahala bẹ silẹ niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun nitori airi owo gba l'awọn ile ifowopamọ si.

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe awọn ọmọ ati olugbe orileede Naijiria n la iṣoro airi owo wọn gba l'awọn ile ifowopamọ kaakiri, bẹẹ si ni epo rọbii naa tun di ọwọngogo kaakiri.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ko din ni ile ifowopamọ mẹta ti awọn olufẹhonuhan dana sun, ti wọn si tun ba àwọn miran jẹ kọja sisọ.

Yatọ si eyi, ọpọ dukia, to fi mọ awọn mọto ni awọn olufẹhonuhan naa dana fun lakoko ikọlu yii.

Wọn ni pupọ awọn ile ifowopamọ yii ni wọn ko kowo sita, bẹẹ si l'awọn ẹrọ igbalode ti wọn fi n san owo nita banki, eyi ti a mọ sí ATM ko ṣiṣẹ.

Ibinu yii ni wọn lo jẹ ki awọn kan bẹrẹ sii pariwo sita, ti wọn si n fẹhonuhan, ko to di pe awọn tọọgi gba a mọ wọn lọwọ, ti wọn sì ṣe ikọlu nla.

Diẹ ree lara awọn aworan ile ifowopamọ to ti dẹnukọlẹ bayii, latari ikọlu naa:














No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI