Ẹ ma ṣe gbiyanju lati yi ibo fun PDP o - Ṣẹgun Ṣowunmi pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 16, 2023

Ẹ ma ṣe gbiyanju lati yi ibo fun PDP o - Ṣẹgun Ṣowunmi pariwo sita


Oludije s'ipo gomina ni igun kan lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) tẹlẹ, Ọtunba Ṣẹgun Ṣhowunmi ti parọwa s'awọn ọmọ ẹgbẹ bayii pe ki wọn ma ṣe gbiyanju lati yi ibo fun ẹgbẹ naa lakoko idibo to n bọ lọna yii.
 
Ṣhowunmi sọ pe ki wọn tẹle ilana ati ofin eto idibo ti ajọ eleto idibo, INEC gbe kalẹ, lati le gba eto idibo oni wọọrọwọ laaye.

Gbajugbaja oloṣelu naa lo sọrọ yii niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa, lakoko to n bawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ṣe ipade l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii.
 
O ni ilana ati ofin eto idibo ọdun 2023 ko nii faaye silẹ fun idibo to pọ kọja awọn oludibo, nitori pe ibudo eto idibo ti ibo ba ti pọ ju awọn oludibo lọ ni ajọ INEC yoo wọgile.
 
“Ibudo idibo ti wọn ba ti rii ti ibo pọ ju awọn oludibo lo, ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission (INEC) yoo wọgilee.”
 
“Ofin eto idibo to wa nita lasiko yii, ko faaye silẹ fun pe ki ibo pọ ju awọn to dibo lọ. Ẹ gbiyanju lati rii pe ibo ti wọn di ko kọja awọn to dibo lọ. Ko si sẹni to ran an yin lati yi ibo.
 
“Ẹ ni lati bojuto ibudo idibo yin. Ojuṣe yin ni lati lọ parọwa s'awọn eeyan lati jade dibo. Ko si yiyi ibo, ẹ dakun!”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI