Lekan Adekanbi, awakọ tọkọ-taya ti wọn pa danu, ko to di pe wọn tun dana sun wọn mọle lọjọ aisun ọdun ti oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii ti sọ pe iṣẹlẹ naa yoo kọ awọn olowo ti kii ṣaanu mẹkunnu lọgbọn.
Ọmọkunrin naa lo sọrọ yii l'ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii nibi ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti f'oju rẹ han f'awọn akọroyin lori ẹsun ipaniyan ati idigunjale ti wọn fi kan an ninu ọgba wọn to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta.
Nibẹ lo ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe kii ṣe erongba oun ni lati ṣeku pa wọn, bi ko ṣe pe koun ja won lole, koun le gba ẹtọ oun lọwọ wọn, ṣugbọn to sọ pe akoko ikọlu naa ni nnkan yiwọ.
Lekan to sọ pe ọdun keje ree toun ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi awakọ jẹ ko di mimọ pe o ti pẹ toun ti n beere fun ẹkunwo lori iṣẹ toun n ṣe fun wọn, ṣugbọn to ni tọkọ-taya naa ko ri toun ro.
O ni lati oṣu kinni, ọdun 2020 loun tii n beere fun ẹkunwo iṣẹ awakọ ti wọn gba oun fun, toun si tun n bẹbẹ pe ki wọn ya oun lowo toun yoo fi bẹrẹ okoowo lati le da duro, ṣugbọn to sọ pe wọn ko da oun loun.
Idi ree to loun fi n wa gbogbo ọna lati gba ẹtọ oun kuro lọwọ wọn.
Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye to jẹ oṣiṣẹ agba nile ifowopamọ banki agba lorileede Naijiria ati iyawo rẹ, Arabinrin Olubukọnla Fatinoye, toun fẹ oṣiṣẹ ile ẹkọ fasiti ọgbin to wa niluu Abẹokuta, iyẹn FUNAAB, to fi mọ ọmọ wọn kan ṣoṣo to ku laye, Ọrẹoluwa Fatinoye lawọn amookunṣeka ṣeku pa l'ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.
Gẹgẹ bi Lekan ṣe ṣalaye, o ni lati nnkan bi aago mọkanla alẹ ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2022 l'awọn ti wa ninu ile awọn oloogbe naa, ko to di pe wọn de ba wọn ninu ile laaarọ ọjọ keji.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe;
"Lekan Ahmẹd Adekanbi lorukọ mi. Ni akọkọ, mo fẹ ki ẹ mọ pe ko si ẹni ti ko da ẹṣẹ ri laye yii, ki Ọlọrun forijin gbogbo wa. Otitọ ọrọ ti mo fẹẹ sọ ninu gbogbo ọrọ to wa nilẹ yii ni pe, mi o ni lọkan lati pa ọga mi gẹgẹ bi Akamọ ṣe sọ. Mi o nii lọkan lati da ẹnikẹni loro nile aye yii.
"Amọ nnkan ti mo fẹẹ sọ ni pe Ọlọrun a san onikaluku lẹsan rẹ. Ṣe ẹ ri nnkan to ṣẹlẹ yii, o maa kọ ọpọlọpọ awọn olowo ti wọn ko laanu, ti wọn n daju mẹkunnu l'ẹkọọ.
"Iṣẹ awakọ lawọn ọga mi gba fun ninu oṣu kẹsan, ọdun 2018. Agbegbe Quarry ni wọn n gbe lagbegbe naa. Yatọ si pe mo n wa mọto wọn, mo tun fọ mọto. Lẹyin oṣu mẹfa ni wọn mu igbalẹ wa wi pe ki n maa ba wọn gba ilẹ inu ile ati ayika, mi o si sọrọ.
"Ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira ni mo n gba. Ọdun 2020 ni mo ba wọn sọrọ wi pe ki wọn ya mi lowo. Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kinni, ọdun 2020 ni emi ati ọga mi jọ lọ s'Ekoo, ibẹ ni mo ti raaye lati sọ fun wọn pe ki wọn ya mi lowo oṣu mi fun ọdun kan, ki emi naa le maa ri nnkan ṣe lẹgbẹẹ an. Wọn si lawọn yoo ṣiṣẹ lori ẹ.
"Ọdun naa jalẹ, wọn ko ṣe ohunkohun, nigba to di ọdun 2021, mo tun ba iyawo wọn sọrọ lori ẹ, awọn naa si lawọn yoo ba ọkọ awọn sọrọ, ṣugbọn sibẹ mi o gbọ nnkankan. Bakan naa lo tun ri lọdun 2022. Inu oṣu kẹfa ni mo tun ran wọn leti, wọn si lawọn ko gbagbe,
"Nigba ti mo rii pe wọn ko ri temi ro, mo lọ ba aburo wọn to mu mi de ọdọ wọn, ẹninaa si loun yoo ba wọn sọrọ. Ọdọọdun si ni wọn paarọ mọto wọn, mọto miliọnu marun-un si mẹwaa naira ni wọn maa n ra. Gbogbo nnkan yii ko ba mi lara mu. Yatọ si iṣẹ ti wọn gba mi fun, mo tun n ba wọn fọ aṣọ, maa tun lọ aṣọ wọn, maa tun ile ṣe fun wọn, bẹẹ ni maa tun fun aja wọn lounjẹ, sibẹ wọn ko fi kun owo oṣu mi.
"Lara awọn ti mo fi ọrọ naa lọ lo jẹ ko ye mi pe beeyan ba ba olowo ṣiṣẹ fun ọdun marun-un, ti ko ba ri nnkan gbeṣe laye, ọdaju ni iru olowo bẹẹ. Atigba naa ni mo ti n wa ronu nnkan ti mo le ṣe lati gba ẹtọ mi kuro lọwọ wọn. Mi o le gba ki wọn lo bi ẹru, ki wọn wa le mi danu lai ni nnkan gidi ti mo ti ṣe lati ara wọn.
"Ẹni ti mo fi ọrọ lọ gba ẹgbẹrun lọna ogoji naira lọwọ mi, lati ba mi wa ibọn, ṣugbọn ti ko gbe ibọn naa wa. Latigba ti mo ti n ba wọn ṣiṣẹ, wọn ko jẹ mi lowo oṣu ri, ṣugbọn wọn ko fi kun owo oṣu mi. Ẹtọ ti mo fẹẹ gba lọwọ wọn ni pe wọn fi kun iṣẹ ti wọn gba mi fun, wọn ko si fi kun owo oṣu mi."
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe ibi toun ti n ronu boun yoo ṣe digun ja wọn lole, loun ti ronu kan Waheed Adeniyi, ẹni ti wọn tun n pe nu Kofi, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun, toun si pe e lori foonu.
O ni Kofi lo gbe ibọn tawọn lo lọjọ naa wa, ki wọn to lọ ka wọn mọle. O ni Kofi lo pe Ahmẹd Ọdẹtọla ti wọn tun n pe ni Akamọ lati jọ ṣiṣẹ.
Siwaju sii lo sọ pe nnkan bi aago mọkanla alẹ lawọn ti wa ninu ile naa, to si ni ṣe ni tọkọ taya naa ba wọn ninu ile nigba ti wọn de lati iṣọ oru aisun ọdun.
Lekan tun sọ pe bi wọn ṣe lawọn ti dunkoko pe ki wọn fi owo ranṣẹ sinu apo aṣuwọn wọn, bo tilẹ jẹ pe ti Akamọ lawọn kọkọ fẹẹ lo, ṣugbọn ti ko lọ, eyi to jẹ koun lo aṣuwọn toun.
O ni ẹgbẹrun mejilelọgọrun naira ni oloogbe naa kọkọ fi ranṣẹ soun, koun to sọ pe owo naa kere, lẹyin naa lo ṣẹṣẹ fi miliọnu kan naira ranṣẹ. O ni Kofi lo dumbu Ọgbẹni Kẹhinde ati iyawo ẹ, Bukọnla Fatinoye, ko to di pe awọn ọmọ wọn de ba wọn.
Bẹẹ lo sọ pe bawọn ọmọ ṣe de, lawọn ti de wọn, ti wọn si lọ ju oku wọn sinu odo lagbegbe Ọbada niluu Abẹokuta.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi to foju awọn ọdaran naa han sọ pe ọjọ keji iṣẹlẹ naa lọwọ tẹ Lekan, ṣugbọn to daku ninu ahamọ, eyi to mu ki wọn sare gbe e lọ si ile iwosan fun itọju. O ni ile iwosan naa ni Lekan ti sare dide lori bẹẹdi, to si fo fẹnsi salọ.
Oyeyẹmi ni eyi lo jẹ kawọn fura pe o mọ nipa bi wọn ṣe sẹku pa tọkọtaya naa ati ọmọ wọn, ti wọn si bẹrẹ iwadii lẹkunrẹrẹ.
Bakan naa lo sọ pe iwadii ti wọn ṣe fidi rẹ mulẹ pe agbegbe Isẹyin ni Lekan salọ lọdọ ẹgbọn rẹ kan, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi debẹ, o tun ti juba ehoro.
Aidawọ iwadii duro lo mu ki ṣalapade rẹ nibi to sapamọ si niluu Abẹokuta, ti ọwọ si tẹ ẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii. Ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun un lo jẹ kọwọ tẹ awọn ọrẹ rẹ meji ti wọn jọ ṣiṣẹ buru naa lagbegbe Ogere lọjọ kẹsan, oṣu keji, ọdun ti a wa yii.
Ni bayii, o sọ pe ọga awọn Frank Mba ti paṣẹ pe ki wọn lọ foju awọn ọdaran naa ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lẹkunrẹrẹ.
No comments:
Post a Comment