Kani iyaale ile ẹni ọdun mọkanlelogoji yii, Elizabeth Arigo Owie mọ pe opin ọsẹ to kọja yii ni yoo jẹ igbẹyin oun loke eepẹ ni, boya ko ba ti jokoo rẹ sile jẹjẹ.
Nibi ti awọn tọọgi ti da wahala silẹ lawọn ibudo idibo kan lagbegbe Ogheghe, ijọba ibilẹ Ikpoba Okha, niluu Benin la gbọ pe ọta ibọn ti ba Elizabeth, iya ọlọmọ mẹta, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe wọn ti kọkọ gun obinrin kan, Efidi Bina Jennifer, nijọba ibilẹ Surulere l'Ekoo, iyẹn nibi t'awọn tọọgi ti da wahala silẹ.
No comments:
Post a Comment