Awọn Ṣọja yinbọn pa eeyan mẹta ni Mowe Ibafo, nitori ifẹhonuhan owo naira tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 19, 2023

Awọn Ṣọja yinbọn pa eeyan mẹta ni Mowe Ibafo, nitori ifẹhonuhan owo naira tuntun


Orin ‘oro nla le da’ lawọn ara agbegbe Mowe si Ibafo to wa lopopona marosẹ Eko siluu Ibadan, ipinlẹ Ogun mu sẹnu l’ọjọ Ẹti tii ṣe Fraide to kọja yii, nigba ti wọno lawọn ẹṣọ aabo ologun orileede yii yinbọn pa eeyan mẹta.

Nibi iwọde ifẹhonuhan si ti ọrọ ti Aarẹ Muhaamadu Buhari sọ lori owo naira tuntun ati ti atijọ, eyi ti awọn eeyan ṣe l'ọjọ Ẹti, Fraide naa ni ijamba yii ti waye.
 
Aarẹ Muhammadu Buhari lo sọrọ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee wi pe awọn owo naira ti a n na tẹlẹ, iyẹn ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun kan naira lowo ti a ko nii na mọ, ati pe igba naira ti a n na tẹlẹ nikan ni yoo wulo fun ọgọta ọjọ gbako, ko to di pe o kasẹ nilẹ.
 
Buhari lo sọrọ naa lakoko to n ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ, to si ni lati le jẹ ki idibo waye lọna to tọ lai si pe oloṣelu kan n fi owo ra ibo.
 

Ifẹhonuhan naa la gbọ pe o bẹrẹ ni nnkan bi aago mẹsan aabọ aarọ ni garaaji Ọtọta to gbajugbaja nipinlẹ Eko, to si tan de agbegbe Ojodu Berger, to paala pẹlu ijọba ibilẹ Ifọ, ko to di pe wọn tan an de agbegbe Mowe Ibafo, to wa n'ijọba ibilẹ Ọbafemi-Owode, ipinlẹ Ogun.
 
Wọn ni niṣẹ ni sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ bẹrẹ, paapaa bi mọto ko tun ṣe kuro loju kan ṣoṣo fun bi wakati marun-un si mẹfa gbako.
 
Eyi ni wọn lo mu k'awọn ṣọja to wa lagbegbe naa binu, ti wọn fi dabọn bọle lati le awọn olufẹhonuhan naa danu, ti ibọn si ba ọpọ awọn eeyan, eyi ti mẹta ku loju ẹsẹ.
 
Lara awọn ti ọta ibọn naa ba la gbọ pe wọn sare gbe lọ si ọsibitu fun itọju, ko ma ba a ku.
 
AWIKONKO gbọ pe lati ọdun to kọja ni owo naira ti di iṣoro nla f'awọn ọmọ Naijiria, to si tun pada yiwọ kọja ohun t'awọn eeyan lero l'ọdun yii, pẹlu bi banki ko ṣe ko owo kalẹ f'awọn eeyan lati na.
 

Koda, ọpọ awọn ẹrọ igbalode ti banki fi n san owo f'awọn eeyan, iyẹn Automated Teller Machines (ATM) kaakiri ni ko ṣiṣẹ, eyi to jẹ iṣoro f'awọn eeyan lati ri owo wọn gba. Bakan naa lawọn eeyan ko tun ri owo fi ranṣẹ lati ori foonu wọn nirọrun.
 
Ifẹhonuhan yii la gbọ pe o mu ki Gomina Dapọ Abiọdun t'ipinlẹ Ogun lati wọgile akanṣe eto to ni lati lọ ṣi iṣẹ akanṣe lagbegbe Mowe lọjọ naa.
 
A gbọ pe lara awọn oṣiṣẹ gomina to maa n ṣaaju lọ wo bi nnkan ṣe n lọ lawọn agbegbe ti gomina ba fẹẹ lọ, iyẹn 'Advance Team', Akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹ akanṣe, Ọgbẹni Benson lawọno tọọgi kọkọ dana iya fun, ti wọn si tun ji foonu rẹ lọ.

Ileeṣẹ panapana ti Gomina Dapọ Abiọdun kọ sagbegbe Mowe Ibafo lo fẹ lọ ṣi lọjọ naa, ki iroyin to tẹ ẹ lọwọ pe nnkan ko fararọ lagbegbe naa, eyi to jẹ ko wọgile e.
 

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Frank Mba ti wa parọwa s'awọn araalu lati maa ni suuru, pẹlu ipenija to wa nita lakoko yii, pẹlu ileri wi pe ẹnikẹni to ba fẹẹ lo anfaani ipenija naa lati da wahala silẹ laaarin ilu yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI