Aṣiri tu! Ko si ẹgbẹ Hausa tabi Fulani kan to darapọ mọ PDP ni Kwara - Miyetti Allah pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 21, 2023

Aṣiri tu! Ko si ẹgbẹ Hausa tabi Fulani kan to darapọ mọ PDP ni Kwara - Miyetti Allah pariwo sita


Ẹgbẹ Hausa Fulani ti a mọ si Miyetti Allah ti wọn wa l'ẹkun ijọba ibilẹ Guusu ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe ko si ọmọ ẹgbẹ awọn kankan to lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Peoples DEmocratic Party, PDP n'ipinlẹ naa.

Wọn ni irọ nla to jinna si otitọ ni awọn eeyan n gbe kaakiri, ati pe ala ti ko le wa si imuṣẹ ni iroyin ẹlẹjẹ naa.
 
Alaaji Ibrahim Muhammed, to gba ẹnu gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ Miyetti Allah sọrọ lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii niluu Ajaṣẹ-Ipo, iyẹ lakoko ti oludije sile igbimọ aṣofin kekere l'Abuja, lẹkun Ekiti, Iṣin, Irẹpọdun ati Oke-Ero, Tunji Ọlawuyi lọ sọ erongba rẹ fun wọn.
 
O ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti ni aṣeyọri to pọ kọja afẹnuroyin ju gbogbo ẹgbẹ to ti ṣakoso sẹyin lọ nipinlẹ ọhun, to si ni ẹgbẹ to n ṣe daadaa lawọn wa lẹyin ẹ, kii ṣe PDP.

Alaaji Mohammed sọ pe ohun ti awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ n gbe kaakiri ni wọn n gbero, to si ni ala ti ko le ṣẹ rara ni ero ọkan wọn.
 
Wọn wa jẹ ko ye oludije naa wi pe awọn yoo gbaruku tii ninu idibo to fẹẹ waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji, ati ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI