Gbajugbaja oṣere Yoruba nni, Adeniyi Johnson ti fi idunnu rẹ han lori ibeji ti iyawo rẹ, Ṣeyi Ẹdun ṣẹṣẹ bi lọjọ Aje, Mọnde, ana, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2023.
Kaakiri agbaye lawọn ololufẹ awọn ilu mọ-ọn-ka oṣere tiata ọhun ti n ki wọn ku oriire lori ayọ ọmọ tuntun yii.
Alẹ ana naa ni Adeniyi Johnson gbe ọrọ idupẹ sori ikanni Insitagiraamu rẹ wi pe 'Asiko Ọlọrun kii pẹ', ati pe ipinnu Ọlọrun fun ẹda laye ga pupọ.
No comments:
Post a Comment