Agbẹnusọ ẹgbẹ ọmọ Yoruba nilẹ Katsina, ipinlẹ Katsina, Alagba Sunshine Olu Akinsulire ti sọ pe gbogbo owo ti oludije s'ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmẹd Tinubu kii ṣe aṣejere, bi ko ṣe aṣedanu lasan.
O ni awọn ọmọ ilẹ Hausa ko ṣetan lati dibo fun Tinubu, nitori pe wọn ko fẹran rẹ, bi ko ṣe pe oju aye lasan ni wọn n ṣe fun un.
Alagba Akinsulire lo sọrọ yii lakoko to n fi ẹhonu rẹ han si awọn iwa aibikita to sọ pe Tinubu n hu s'awọn Yoruba to wa l'oke-ọya, iyẹn nilẹ Hausa, paapaa bo ṣe ni kii beere awọn ni gbogbo igba to wa ti wa sibẹ.
Ọkunrin naa sọ pe bi Tinubu ba fẹẹ wa si ilẹ Hausa, gbogbo ọmọ Yoruba to wa nibẹ pata lawọn yoo dana ariya, ti wọn yoo si korajọ lati pade ẹ, ṣugbọn to ni iyalẹnu lo maa n jẹ wi pe Tinubu kii wo ọdọ awọn, bẹẹ si ni kii fun wọn lowo lati fi mọ riri awọn.
Baba naa ni kaka ki Tinubu mọ riri awọn, niṣe lo maa n gbe owo nla f'awọn Hausa ati Fulani, awọn to sọ pe ọrẹ ojulasan ni wọn n ṣe fun un.
"Ẹ dakun, ẹ ba wa beere lọwọ Aṣiwaju Tinubu wi pe ẹṣẹ wo ni awa ọmọ Yoruba to wa ni oke-ọya ṣẹ ẹ? To ba ti wa, kii fẹẹ lati ri Yoruba to wa ni oke-ọya, awọn Hausa ati Fulani lo n gbe owo fun.
"Tinubu wa si Katsina laipẹ yii, ọgọrun miliọnu naira lo n gbe fun wọn. Bo ṣe n fun awọn Ẹmir lowo, naa lo n fun awọn ọmọ ilu naa lowo. Ṣugbọn ko ranti awa ọmọ Yoruba ti a wa nibẹ ri.
"Ko fun ọba Yoruba to wa ni oke-ọya lowo ri. Ọba Yoruba to wa ni Katsina, Ọba Oluwakẹmi Mustapha pe ọba Yoruba to wa ni Ṣokoto, ti wọn si jọ sọrọ pe Tinubu ko fun awọn lowo kankan nigba to wa sibẹ. Bẹẹ naa lo ri lọdọ ọba Yoruba Gusau, Alaaji Ṣolankẹ.
"Ẹṣẹ wo ni awa Yoruba ṣẹ Tinubu ti kii fi ranti wa. Ko sigba ti Tinubu wa, ti awa ọmọ Yoruba kii wọ aṣọ ẹgbẹjọda lati pade ẹ, ti a si ma maa kọrin tẹle lẹyin, ṣugbọn kii ri ti wa ro rara. Gbogbo ojuṣe to yẹ la n ṣe lati ṣagbatẹru Tinubu, ṣugbọn ko fi igba kan dupẹ lọwọ wa ri, awọn Hausa ati Fulani lo n gbe owo fun.
"Ko yẹ ko maa ri bẹẹ, nitori pe ẹni ti a nigbagbọ pe o le tukọ Naijiria niyẹn. Ọmọ ale ni Tinubu, nitori pe ko fẹran ọmọ iya rẹ. Ti Tinubu ba gbe owo fun Hausa ati Fulani, niṣe ni wọn maa yinmu sii wi pe owo to ji ko lo n ko lo n fun awọn, ati pe awọn ko nii dibo fun un.
"Awọn ọlọkada to jẹ Hausa ni wọn wa fi owo han mi laipẹ yii wi pe owo ti Tinubu fun wọn niyẹn nigba to wa. Omi bọ loju mi ni, nitori pe ko ranti awa Yoruba ti a wa nibẹ.
"Tinubu ṣe bẹẹ ni Ṣokoto, Zamfara, Katsina, ṣugbọn mi o le sọ boya bẹẹ naa lo ri ni Kano. Bi Tinubu ṣe wa lọdun to kọja niyẹn ti ko beere Yoruba, ko si yẹ ko maa ri bẹẹ. Wọn si ni ọmọ ale Yoruba lo maa fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ, bẹẹ lọrọ Tinubu ṣe ri bayii o.
"Awọn Hausa ti Tinubu n ko owo fun, niṣe ni wọn sọ pe owo to n ji ko lawọn n gba ti wọn nibẹ, awọn ko nii dibo fun un. Aṣedanu lo n ṣe ni oke-oya, kii ṣe aṣejere. Awolọwọ ko jẹ ṣe iru ẹ. Bi ẹ ba ranti Awolọwọ ninu itan, ko si ibi to de, ti kii beere ọmọ Yoruba.
"Ọrọ Tinubu n kọ wa lominu, o si n ba wa ninu jẹ. Tinubu lọ ki awọn to pa ara wọn ni Bakori ni Katsina, ọgọrun miliọnu naira ni Tinubu gbe silẹ fun wọn, o tun fun Ẹmir Katsina ni ọọdunrun miliọnu naira, bẹẹ naa ni Ẹmir Katsina, Ẹmir Daura naa gba ọgọrun miliọnu naira.
"Awọn ti awọn Boko Haram pa awọn obi wọn danu, Tinubu fun wọn ni ọgọrun miliọnu naira. Bẹẹ lo n pin owo kaakiri bẹẹ. Gbogbo bo ṣe n na owo yii, ni iroyin n tẹ wa lọwọ. Ọmọ ale ti a tun ni lasiko yii ni Tinubu."
No comments:
Post a Comment