Arsenal lulẹ tiyanu-tiyanu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 4, 2023

Arsenal lulẹ tiyanu-tiyanu


Niṣe ni gbogbo awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal kawọ lori lọsan oni, ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu alatako wọn, Everton ṣe wọn baṣubaṣu.

J. Tarkowski lo dabaru ifigagbaga naa to waye ni papa iṣere Goodison Park mọ Arsenal loju, ti wọn ko si mọ ohun ti wọn le ṣe mọ.

Gbogbo galegale Arsenal ati awọn ololufẹ wọn lo rọ walẹ lonii, lẹyin ti wọn lulẹ niwaju Everton pẹlu aami ayo kan si odo.

Ẹru la gbọ pe o ti n ba Arsenal atawọn ololufẹ wọn, nitori to ti n fi han pe o ṣee ṣe ki ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City gba liigi naa mọ wọn lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI