Ile ẹjọ Majisireeti to wa ni Iṣabọ niluu Abẹokuta ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi Lekan Adekanmbi ati awọn ọrẹ rẹ to pa tọkọtaya lọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2023 yii pamọ sọgba ẹwọn, titi digba ti igbẹjọ miran yoo fi waye.
Ọgba ẹwọn ti Ọba ni ile ẹjọ naa paṣẹ pe ki wọn lọ fi Lekan, Ahmẹd Ọdẹtọla ati Waheed Adeniyi pamọ si, ki wọn si fi iya ẹ, Adenikẹ Adekambi ati iyawo afẹsọna ẹ pamọ sọgba ẹwọn Ibara niluu Abẹokuta.
Gẹgẹ bi Onidajọ Esther Idowu ṣe paṣẹ naa lonii Ọjọru, Wẹsidee, o ni ọgọta ọjọ tii ṣe oṣu meji gbako ni k'awọn afurasi ọdaran naa fi gbatẹgun lọgba ẹwọn.
Yatọ si awọn marun-un naa, Onidajọ Idowu tun paṣẹ pe ki wọn fi awọn meji to ra mọto awọn oloogbe naa nirakura, Owolaja Anuoluwapọ ati Usman Azeez pamọ sọgba ẹwọn Ọba kan naa.
Awọn wọnyii ni wọn lọwọ si iku Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye; iyawo ẹ, Bukọla Fatinoye ati ọm, idunjaleọ wọn, Ọrẹoluwa Fatinoye lọjọ Aisun ọdun.
No comments:
Post a Comment