Baba agbaaya kan ti ọwọ tẹ laipẹ lori ẹsun wi pe o n ko ibasun fun ọmọ iyawo to ṣẹṣẹ n fẹ ti sọ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe asiko toun ba ti mu ọti yo loun maa n ba ọmọ naa laṣepọ laaarin oru.
David Gaius lorukọ ọkunrin naa ti wọn sọ pe ẹẹmẹta ọtọọtọ lo ti ko ibasun fun ọmọ naa, ati pe yoo tun fi aṣọ funfun pa oju ara ọmọ ọhun lẹyin to ba ṣetan.
Ipinlẹ Adamawa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, ni agbegbe kan ti wọn n pe ni Unguwan Prison, abule Dirma, Dumne ijọba ibilẹ Song.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Suleiman Nguroje ṣe ṣalaye, o ni ko si ọrọ meji ti David n sọ, bi ko ṣe pe 'iṣẹ eṣu ni'.
O ni eṣu lo maa n tan oun jẹ lati lọ ba ọmọ naa laṣepọ nigba toun ba ti mu ọti yo kẹri.
Bakan naa ni David tun sọ pe loootọ loun maa n lo oogun ifẹ lati jẹ ki ọmọ naa nifẹ oun, ati pe inu ẹran toun maa n fun un jẹ, loun n fi oogun ifẹ naa si.
Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe ọdun 2020 loun kọkọ fipa ba ọmọ naa laṣepọ, iyẹn nigba to wa lọmọ ọdun mẹrinla.
Nigba to n sọ bi ọwọ ṣe tẹ ẹ, o ni iyawo oun to jẹ iya ọmọ naa lo ka oun nibi toun ti n ba ọmọ naa laṣepọ karakara ni igba kẹta.
Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe kii ṣe nitori oogun owo loun ṣe n ba ọmọ naa laṣepọ.
No comments:
Post a Comment