Olupako tiluu Ṣaarẹ, Ọba Haruna Ọlawale Suleiman ti sọ pe asiko lati san ẹsan awọn iṣẹ rere ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe silẹ ree, to si ni k'awọn jade lati dibo fun un nibi ibo gomina to n bọ laipẹ yii.
Ọba Suleiman, Penpebiaṣa keji lo sọrọ naa, nibi akanṣe adura ti alatilẹyin APC tiluu Ṣaarẹ ṣe fun gomina naa, ko le pada wọle saa keji, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii.
Nibẹ naa ni wọn tun ti lo anfaani rẹ lati ṣadura fun oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmẹd Tinubu, ati gbogbo awọn oludije labẹ asia APC kaakiri ipinlẹ naa.
Mọṣalaṣi agba tiluu Ṣaarẹ, iyẹn 'Share Central Mosque' ni akanṣe adura naa ti waye, eyi ti Imaamu agba ilu Ṣaarẹ ati awọn olori ẹsin Isilaamu niluu Ṣaarẹ ti gbadura.
Nibẹ ni Olupako ti sọ pe ipa ti Gomina AbdulRazaq ti ko ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ naa, ko ṣee fọwọ rọ sẹyin, ati pe ipa rere lo fi lelẹ ninu iṣakoso rẹ.
O ni bawọn ba ti ni iru AbdulRazaq tipẹ ni, o ṣee ṣe ko jẹ pe ipo kinni ni ipinlẹ naa yoo wa lorileede Naijiria, ati pe bẹẹ naa, Kwara ti wa ninu iwe agbaye, paapaa ilẹ Afrika.
No comments:
Post a Comment