Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmẹd Tinubu ati Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ipade niluu Abuja.
Aarọ oni, Ọjọru, Wẹsidee la gbọ pe Tinubu ati Buhari ṣepade bonkẹlẹ nilegbe aarẹ to wa ni Aso Rock.
Ipade ikọkọ naa la gbọ pe o waye ṣaaju ipade awọn agbaagba, iyẹn Federal Executive Council (FEC) meeting.
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, la ko tii le sọ pato ohun ti Tinubu ati Buhari jọ so, ṣugbọn sibẹ, wọn ni lori eto idibo to n bọ lọna yii ni ipade naa da lori.
No comments:
Post a Comment