2023: Pasitọ Oyedepo sọ Aarẹ ti awọn ọmọ Naijiria gbọdọ dibo fun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 19, 2023

2023: Pasitọ Oyedepo sọ Aarẹ ti awọn ọmọ Naijiria gbọdọ dibo fun


Alaṣẹ, apaṣẹ ati oludasilẹ ijọ Living Faith Church ti awọn eeyan tun mọ si Winners’ Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo, ti parọwa si gbogbo awọn ọmọ Naijiria patapata lati dibo fun ẹni ti ọkan wọn yan, ti wọn si n'igbagbọ ninu ẹ.

Ọjọ Abamẹta, Satide to n bọ lọna yii ni eto idibo apapọ ọdun 2023 yoo waye, nibi ti gbogbo awọn ọmọ Naijiria yoo ti yan Aarẹ tuntun ati awọn aṣofin, to fi mọ awọn aṣoju-ṣofin ti yoo ṣakoso fun ọdun mẹrin miran 

Biṣọọbu Oyedepo sọ pe fun alaafia ati ilọsiwaju Naijiria loun wa fun.

Agba Ojiṣẹ Ọlọrun naa lo sọrọ yii lakoko to n waasu ninu isin to waye ni ṣọọṣi ẹ lonii, ọjọ Aiku, Sannde.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe Naijiria kii ṣe ẹnikan ṣoṣo, bẹẹ si ni kii ṣe ogun ẹnikẹni, bi ko ṣe apejọpọ awọn eeyan ti wọn ko si fun tita.

“Fun alaafia ati ilọsiwaju Naijiria ni mo wa fun, Naijiria ko si fun tita. A kii ṣe eeyan kan ṣoṣo tabi ogun ẹnikẹni, apejọpọ eeyan la jẹ, bẹẹ la ko si fun tita.”

Nigba to n sọrọ lori ẹni ti awọn eeyan ni lati dibo fun, Biṣọọbu Oyedepo sọ pe;

“Ẹ ko nilo olowo biliọnu tabi olowo rẹpẹtẹ lati di aarẹ, ẹ nilo ẹni to ni agbara, ẹ nilo ẹni to ni iwa, bẹẹ la si ni wọn ni gbogbo igun to wa ni orileede yii 

“Gbogbo eeyan lo ni ẹtọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu to ba wuu, ṣugbọn bi ẹ ko ba darapọ mọ alaafia orileede yii, inu ewu nla lẹ wa. O maa gba idasi pajawiri lati ji orileede yii pada dide kuro ninu ajalu nla.

“Ọsẹ ẹtanjẹ la fẹẹ wọ yii, nitori naa, ẹ dibo pẹlu ọgbọn ori. Ẹ dibo fun adari to ni agbara ati iwa rere.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI