Aarẹ Muhammadu Buhari ti orileede Naijiria ti parọwa si gbogbo ọmọ orileede yii lati dibo fun oludije s'ipo aarẹ lọdun 2023 to ba wu wọn lọkan.
Aarẹ Muhammadu Buhari ti orileede Naijiria ti parọwa si gbogbo ọmọ orileede yii lati dibo fun oludije s'ipo aarẹ lọdun 2023 to ba wu wọn lọkan.
Bẹẹ lo ni ki wọn dibo wọn fun ẹni ti wọn ba n fẹ lai bẹru ohunkohun nitoi pe gbogbo eto lo ti pari lori eto aabo fun eto idibo to n bọ lọna yii.
"Ẹyin eeyan mi, lọjọ karundinlọgbọn la maa lọ yan Aarẹ ati awọn aṣofin ti a fẹ. Mo si mọ pe eto ati ilana owo to wa nita lasiko yii ti ko ipa rere, to si ti din nina owo sinu oṣelu ku.
"Igbesẹ rere leyin jẹ, to si tun jẹ igbesẹ akikanju ati ilana rere ti iṣakoso yii fẹẹ fi lelẹ, paapaa ipilẹ rere fun idibo to ṣojuṣara.
"Mo fẹẹ rọ gbogbo ọmọ Naijiria, lati jade lọ dibo fun oludije ti wọn ba n fẹ lai bẹriu, nitori pe a maa pese eto aabo to yẹ, wọn yoo si ka ibo yin.
"Bakan naa, mo fẹẹ rọ yin pe ki ẹ dẹkun iwa to le dabaru eto idibo yii."
No comments:
Post a Comment