2023: Awọn agbaagba Ariwa Kwara f'ọkan AbdulRazaq balẹ lori idibo to n bọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 13, 2023

2023: Awọn agbaagba Ariwa Kwara f'ọkan AbdulRazaq balẹ lori idibo to n bọ


Gbogbo awọn agbaagba ati alẹnulọrọ lẹkun Ariwa ipinlẹ Kwara ni wọn ti sọ fun gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq lati lọ f'ọkan ara rẹ balẹ, nitori pe awọn yoo gba gbogbo agbegbe naa fun un ninu eto idibo to n bọ lọna l'oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii.
 
Ọsẹ to kọja yii lawọn agbaagba naa ti Aṣoju Nurudeen Muhammed lewaju wọn, lọ ṣe abẹwo si Gomina AbdulRazaq, nibi ti wọn ti ṣe ipade bi nnkan yoo ṣe lakoko eto idibo to n bọ.
 
Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe gomina wọn ti na ọwọ mudunmudun eto iṣẹjọba awaarawa si gbogbo ẹkun to wa n'ipinlẹ naa, paapaa ẹkun Ariwa Kwara ti awọn ti wa.
 
Wọn ni gbogbo awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ti gomina ṣe lọdun mẹta le diẹ sẹyin lawọn ri ipa rẹ, to si fọkan awọn balẹ wi pe ọjọ iwaju rere f'awọn, paapaa iran to n bọ lẹyin.

Lara awọn agbaagba naa ni; alaga ijọba ibilẹ Kaiama tẹlẹri, Alaaji Inuwa Musakallah; Ọnarebu Abdulmumin Sidik Katibi; Alaaji Abubakar Ndakene; Oloye Wọle Ọkẹ.

Awọn miran ni; Ciroman tiluu Kaiama, Alaaji Abubakar Omar; Ọnarebu Abdulkareem Ayinde; ati Atiku Abdulsalam toun jẹ alaga igbimọ agbaagba Ariwa Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI