2023: Aderinokun lo ni ibo ni ile ipagọ Ridiimu - Awọn alakoso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 19, 2023

2023: Aderinokun lo ni ibo ni ile ipagọ Ridiimu - Awọn alakoso


Awọn alakoso eto oṣelu ninu ijọ Ridiimu to wa ni Mowe, iyẹn Director of politics in Redemption Camp, ti Pasitọ Akande jẹ olori wọn ti sọ pe awọn ko ni oludije meji tawọn yoo dibo fun, fun ipo aṣofin agba lorileede yii, lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, to kọja oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP, Olumide Aderinokun.
 
Pasitọ Akande ni awọn yoo ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe gbogbo awọn oludibo lagbegbe naa ni wọn dibo fun Aderinokun, nitori pe oun nikan lẹni to kaju oṣuwọn fun ipo aṣofin agba naa.

Nibi ipade ni Aderinokun pẹlu awon agbaagba ilu Owode, to fi mọ oludije sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, John Tosin ni Pasitọ Akande ti ṣeleri naa, to si ni gbogbo awọn olugbe inu ọgba Ridiimu naa ni wọn ti ṣetan lati dibo fun ọjọ iwaju rere l'ọjọ Abamẹta, Satide to n bọ lọna.
 
Bakan naa lo sọ pe awọn ti gbe igbesẹ lati rii pe gbogbo awọn eeyan gba kaadi idibo alalopẹ, iyẹn PVC wọn, lati le kopa ninu eto idibo to n bọ lọna yii.
 
Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Aderinokun dupẹ gidigidi lọwọ awọn alakoso naa, to si ni oun ti ri idi pataki ti awọn ijọ fi gbọdọ maa da si ọrọ oṣelu, paapaa lorileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI