Ijọba ipinlẹ Kwara ti bu ọwọ lu Ọmowe Jawondo Ayinde Sheu gẹgẹ bi adele ọga agba ile ẹkọ awọn olukọni tiluu Ilọrin, Ilorin College of Education.
Yiyan ti wọn yan Ọmọwe Sheu la gbọ pe o lọ nibamu pẹlu bi ijọba ipinlẹ naa ati awọn alaṣẹ Kọlẹẹji ọhun ṣe tọwọ bọwe adehun, ti wọn si fẹnuko.
Ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii ni iṣẹ bẹrẹ labẹ ofin lẹkunrẹrẹ, lai fi akoko ṣofo.
A gbọ pe wọn yan Ọmọwe Sheu lẹyin ti wọn yọ adele tẹlẹ, Ọmọwe Jimọh Ahmẹd Ayinla, ti wọn si ni koun rọpo ẹ loju ẹsẹ
Ọmọwe Sheu ni ọga agba (Dean) ni ẹka ikẹkọọ imọ ede, iyẹn School of languages.
No comments:
Post a Comment