Wọn le Frank Lampard danu lẹgbẹ agbabọọlu Everton - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 23, 2023

Wọn le Frank Lampard danu lẹgbẹ agbabọọlu Everton


Ẹgbẹ agbabọọlu Everton ti juwe ọna ile fun gbajugbaja akọnimọọngba wọn, Frank Lampard, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe ifasẹyin lo n fa fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu, ti wọn si l'awọn ko nilo rẹ mọ.
 
Bo tilẹ jẹ pe Everton ko tii ri akọnimọọngba tuntun ti yoo dari ẹgbẹ naa, sibẹ, wọn ni ki Lampard maa lọ sile, ati pe ko yẹ lẹni to n tukọ ẹgbẹ agbabọọlu ọhun.
 
Wọn ni kaka ki Lampard maa gbe wọn gun oke, isalẹ tabili ni wọn duro si, ti wọn tun n ja lọ silẹ patapata ninu idije Premier League.
 
Oṣu mejidinlogun lo ku ki asiko Lampard pe pe gẹgẹ bi akọnimọọngba ẹgbẹ agbabọọlu Everton, gẹgẹ bi iwe adehun to tọwọ bọ lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2022.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI