Bo tilẹ jẹ pe inu oṣu kẹsan, ọdun 2018 ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, sibẹ titi di asiko yii niṣẹlẹ naa ṣi n jẹ iyalẹnu, to mu ki awọn kan maa beere pe 'ta ni eniyan Ọlọrun'?
Pasitọ Ọṣhọ ni wọn pe orukọ pasitọ naa ti wọn ka mọ ori ọkan lara awọn ọmọ ijọ, nibi ti awọn mejeeji ti n ko ibasun funra wọn karakara ninu igbo to wa lori oke ti wọn ti lọ gbadura.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, obinrin naa ti wọn pe ni Arabinrin Ajibade la gbọ pe o lọ si ori oke ti pasitọ naa wa lati lọọ gbadura ati aawẹ ọlọjọ mẹta, ṣugbọn to jẹ pe kaka ko kojumọ nnkan to ba lọ, nnkan min in lo n ṣe.
Ohun ta a gbọ ni pe gbara ti Arabinrin Ajibade ti de si ori oke naa ti wọn ni ilu Ibadan lo wa ni wọn l'awọn kan ti bẹrẹ sii fura sii, paapaa pẹlu iṣesi oun ati pasitọ Ọṣhọ.
Idi ni yii ta a gbọ pe awọn eeyan naa fi bẹrẹ sii ṣọ wọn lọwọ-leṣe lati mọ nnkan to pa wọn pọ, ṣugbọn ta a gbọ pe aṣiri wọn pada tu sita.
No comments:
Post a Comment