Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun ti ṣe ileri fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa ti wọn wa labẹ eto SURE-P, wi pe wọn yoo gba biliọnu kan naira ninu biliọnu meji ataabọ naira, eyi to jẹ owo oṣu ajẹẹlẹ wọn.
Ninu owo naa ni ijọba tun ti sọ pe awọn yoo san owo f'awọn oṣiṣẹ naa tẹlẹ, ati gbogbo awọn to ti fẹyinti patapata kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to sọ ipinlẹ ọhun papọ.
Owo yii la gbọ pe awọn iṣakoso to ti kọja lọ ti jẹ silẹ de iṣakoso to wa nibẹ bayii.
Kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ, oye jijẹ ati idagbasoke agbegbe, Ọnarebu Lafia Aliyu Kora-Sabi lo f'idi iroyin naa mulẹ, nibi ipade to ṣe pẹlu awọn alẹnulọrọ ti ọrọ kan.
O ni ijọba tun ti ya biliọnu kan naira sọtọ, gẹgẹ bi wọn ti ṣe tẹlẹ lati san gbogbo gbese ajẹẹlẹ to ti wa nilẹ tipẹ, ati pe gbogbo awọn to di ipo oṣelu mu labẹ eto ijọba ibilẹ laaarin ọdun 1999 si ọdun 2016, to fi mọ owo ifẹyinti ati ajẹmọnu ni wọn yoo san patapata ninu owo ọhun.
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe wọn tun ti ya awọn owo kan sọtọ ninu owo naa lati fi ṣe awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke lawọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun
No comments:
Post a Comment