Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ana lorileede Naijiria, Bukọla Saraki ni iroyin fi to wa leti pe o ti padanu ninu ẹjọ to pe awọn ajọ to n ri si iwa ajẹbanu, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC; Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission, ICPC ati awọn miran.
Ile ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Abuja lo wọgile awọn ẹjọ mejeeji ọtọọtọ naa lonii, Ọjọru, Wẹsidee.
Saraki lo gbe ajọ EFCC, ICPC; Code of Conduct Bureau, CCB; Adajọ agba orileede yii, ọga ọlọpaa orileede yii ati ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọ sile ẹjọ.
Onidajọ Inyang Ekwo nigba to n wọgile ẹjọ naa sọ pe ẹsun ti wọn pe ko lẹsẹ nilẹ, ati pe awọn agbẹjọro to pe ẹjọ ko si nile ẹjọ.
Ẹsun naa ni nọmba wọn jẹ FHC/ABJ/CS/507/2019 ati FHC/ABJ/CS/508/2019.
No comments:
Post a Comment