Awọn agboole Ọdọfin niluu Ijẹja, Ẹgba, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ti sọ pe awọn ti jawe lọ gbele ẹ fun aṣoju wọn nile Ogboni, iyẹn Oloye Sunday Oluwọle.
Wọn ni ki ọkunrin naa yee pe ara rẹ ni aṣoju ilu Ijẹja nile Ogboni wọn, ati pe ki ẹnikẹni ma ṣe ba a ni ohunkohun papọ mọ.
Ninu iwe ẹsun ti wọn fi kan Oloye Sunday Oluwọle, eyi ti agbẹjọro wọn, Hassan Amusa & Co kọ jade, to fi ranṣẹ si igbimọ ọba ati oloye niluu Ẹgba, (Egba Traditional Council) Ake, Abẹokuta ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn ko fẹ Oloye Oluwọle mọ gẹgẹ bi aṣoju awọn.
Yatọ si igbimọ lọbalọba atawọn oloye ti wọn fi iwe ẹsun naa ranṣẹ si, wọn tun fi ranṣẹ si olori Ebi Ọdọfin tiluu Ijẹja, Ẹgba.
Iwe ẹsun naa ti Alaaji Sẹmiu Lawal, Baalẹ abule Ọdọfin Ijẹja; Alagba E. O. Ọlatomi, akọwe agboole Ọdọfin; Alaaji Surajudeen Lawal, Mufasir Musulumi Ijẹja ati Alagba Ọbayọmi Olori Ẹbi ni wọn ti sọ pe ki awọn oloye ilu Ijẹja ma ṣe ni ohunkohun lati ṣe pẹlu Oloye Sunday Oluwọle mọ nile Ogboni, ati pe wọn ko gbọdọ rii gẹgẹ bi aṣoju awọn.
Bakan naa ni wọn lawọn ti ti fi to Ogboni Ijẹja, Ogboni Ẹgba, Olorogun Ologun Ijẹja ati Ẹgba, Parakoyi Ijẹja ati Ẹgba leti.
Ọkan lara awọn mọlẹbi naa to b’AWIKONKO sọrọ jẹ ko ye wa pe niṣe ni Oloye Sunday Oluwọle lọ sori redio, to si lọ sọ pe ki wọn da awọn oloye kan duro niluu Ijẹja, eyi ti wọn ni ko ni aṣẹ lati ṣe bẹẹ.
Ẹni naa ti a fi orukọ bo laṣiri jẹ ko ye wa pe Oluwo ilu nikan lo ni aṣẹ lati lo kede tabi sọrọ lorukọ ilu, kii ṣe Ọdọfin.
Siwaju sii lẹni naa sọ pe ọrọ ti Ọdọfin tori rẹ lọ sori redio yii wa ni kọọtu, idajọ ko si tii waye, eyi to jẹ pe o lodi s’ofin.
Eyi lo fa a ti awọn ara agboole Oluwọle fi dide lati takoo wi pe ko lẹtọọ lati lọ kede lori redio, ti wọn si ni iwa to ko itiju nla ba idile awọn niyẹn, fun idi eyi, wọn ni ko lọ rọkunle.
Wọn ni iru eeyan bii Sunday Oluwọle ko yẹ lẹni to n ṣoju awọn nile Ogboni ilu Ijẹja mọ.
Gbogbo akitiyan lati ba Oloye Sunday Oluwọle sọrọ lori iṣẹlẹ yii lo ja si pabo titi digba ti a pari akojọpọ iroyin yii.
No comments:
Post a Comment