Igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti gbe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹtadinlọgọta (57) rẹ lọ sile awọn ọmọ alailobii ti Stella Ọbasanjọ to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa.
Oni, ọjọ kẹjọ, oṣu kinni, ọdun 2023 ni igbakeji gomina ọhun n ṣayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, nibi ti awọn ẹbi, ọrẹ ati ololufẹ rẹ kaakiri agbaye ti n kii ku oriire, ti wọn si n fi adura ranṣẹ sii.
AWIKONKO gbọ pe Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele ko oriṣiriṣi ẹbun ọkan-o-jọkan lọ f'awọn eeyan naa, eyi to fi n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani to tun ni lati wa laye lonii, paa fun ti awọn aṣeyọri rẹ laye.
Nibẹ lo ti dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ patapata, paapaa awọn oṣiṣẹ rẹ, to fi mọ mama rẹ to ti d'oloogbe fun aduroti wọn.
Lara awọn nnkan ti a gbọ pe Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele fi ta awọn ọmọ alailobii naa lọrẹ ni firiiji ati maṣiini ifọṣọ igbalode, ti wọn si ge akara oyinbo.
Diẹ ree lara awọn fọto bi eto naa ṣe lọ:
No comments:
Post a Comment