Oriire nla! Ileeṣẹ IAS fun awọn oṣiṣẹ mẹtalelogun ni ilẹ to to miliọnu meje naira l’Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 16, 2023

Oriire nla! Ileeṣẹ IAS fun awọn oṣiṣẹ mẹtalelogun ni ilẹ to to miliọnu meje naira l’Abẹokuta


Yoruba bọ, wọn ni ‘yin-ni-yin-ni k’ẹni o le ṣe min-in’, ati pe ‘bi awo ba ki fun ni, o yẹ ka ki fun awo pada’, lo mu ki gbajugbaja ileeṣẹ to n ta ilẹ n’ipinlẹ Ogun, IAS Homes and Properties Nigeria Limited fi ẹbun ilẹ ta awọn oṣiṣẹ ti ko din ni mẹtalelogun lọrẹ, lati fi mọ riri ipa ti wọn n ko ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ileeṣẹ naa.

Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ IAS, Ọgbẹni Ayọbami Adelani lo kede fifi ẹbun ta awọn oṣiṣẹ yii lọrẹ nibi ayẹyẹ ọlọdọọdun ti idupẹ ibẹrẹ ọdun tuntun, ẹlẹẹkẹrin iru ẹ, ti wọn ṣe ninu gbọngan ayẹyẹ otẹẹli Imperial to wa lagbegbe Quarry niluu Abẹokuta ipinlẹ Ogun lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.

Nibẹ ni wọn tun ti tọwọ bọwe adehun pẹlu gbajugbaja oṣere tiata meji, Adewale Alebioṣu ati Bọsẹ Arẹgbẹṣọla, to fi mọ onkọrin musulumi nni, Bukọla Alayande t’ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ere Asalatu lati jẹ aṣoju (Ambassador) ileeṣẹ naa.


Ẹsẹ ko gbero rara ninu gbọngan naa, nibi ti awọn ololufẹ ati onibara ileeṣẹ IAS ti peju-pesẹ lati ba wọn ṣayẹyẹ ọhun, ti wẹjẹ-wẹmu alailẹgbẹẹ si ṣẹlẹ nibẹ. A gbọ pe onikaluku lo lọ n bu ounjẹ ati ọti funra rẹ.

Bakan naa ni ileeṣẹ IAS tun fi Estate tuntun ti wọn pe ni Nigeria Immigration Treasure City to wa niluu Wasinmi, ijọba ibilẹ Ewekoro lelẹ, eyi to l’awọn ti bẹrẹ sii ta f’awọn onibara wọn.

Nigba to n sọrọ, o ni “Ọlọrun nikan ni ọba ti ẹda le fẹyinti, ti itẹsiwaju le da ba iru ẹda bẹẹ nile aye, lẹyin Ọlọrun, ko sẹlomiran mọ. Mo wa nibi lati kii yin kaabọ, ki n si sọ ibi ti a ba iṣẹ wa de. Mo fẹ sọ fun un yin pe bi a ṣe maa n ṣe nileeṣẹ wa ree ni gbogbo ibẹrẹ ọdun.

“A kii ṣayẹyẹ opin ọdun, ayẹyẹ ọdun tuntun la maa n ṣe, idi si ni pe igbagbọ wa ni pe o yẹ ka fi ibẹrẹ ọdun le Ọlọrun lọwọ daadaa, ki o le jẹ ki ipari dara. Ileeṣẹ IAS maa pe ọdun keje to ba di ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa, ọdun 2023 yii.

“Ti wọn ba n sọrọ nipa awọn ileeṣẹ to n ta ilẹ nipinlẹ Ogun lonii, ipo akọkọ la wa lati bi ọdun mẹrin sẹyin, ṣiṣẹ daadaa lo jẹ ka ri ipo naa mu. Gbogbo nnkan to le jẹ ka maa mu oke la maa n ṣe. Lotitọ la n ta ilẹ inu igbo, bi ilẹ ba ṣe jinna si ni owo rẹ ṣe n kere si.


“Ọpọ igba ti a ba mu awọn eeyan lọ si ori ilẹ wa ni wọn maa n sọ pe ibẹ ti jinna ju, iye owo teeyan ba ko dani lo maa sọ iru ibi ti ilẹ rẹ yoo wa. Eyi si maa n jẹ ki awuyewuye wa laaarin awa ati awọn onibara wa. Bi a ṣe ni ilẹ olowo nla, naa la ni olowo kekere. Eeyan ko le fẹẹ ra ilẹ olowo nla, ki a mu iru ẹni bẹẹ lọ sinu igbo, ko ṣee ṣe.

“A ti n kuro nibi ilẹ olowo kekeeke, a ti n lọ sibi ilẹ olowo nla. Ẹgbẹ alajẹṣẹku ti ileeṣẹ Nigeria Immigration Service, ẹka ti ipinlẹ Ogun lo ta ilẹ fun wa, idi ti a fi sọ orukọ wọn niyẹn. A ti bẹrẹ iṣẹ lori ẹ bayii, a si ti n ta ilẹ nibẹ. Nigba ti yoo ba fi di ipari oṣu kẹta si ibẹrẹ oṣu kẹrin, a maa fi ibẹ lelẹ.”

Nibẹ lo tun ti fun awọn onibara, atawọn ololufẹ wọn ni ẹbun pataki ati awọọdu lati mọ riri bi wọn ṣe nigbagbọ ninu wọn, ti wọn si n ba wọn fi owo dokoowo.

Nigba to n sọ idi pataki to fi fun awọn oṣiṣẹ naa ni ilẹ pulọọti kọọkan, o ni kii ṣe gbogbo oṣiṣẹ loun fun ni ilẹ, bi ko ṣe awọn to n ṣe daadaa julọ. O loun mọ riri ipa ti awọn oṣiṣẹ naa n ko ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ileeṣẹ wọn.
 

O jẹ ko di mimọ pe ilẹ toun fun wọn ko din ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira, ati pe nnkan to ba wu onikaluku wọn lo le fi ilẹ naa ṣe, yala ki wọn tun un ta, tabi ki wọn fi kọ ile.
 
Alaaja Tolu Aderounmu, ọkan lara awọn onibara ileeṣẹ IAS nigba to n sọrọ sọ pe inu oun dun lati ba ileeṣẹ naa dowopọ. O ni inu redio loun ti gbọ nipa ileeṣẹ naa, toun si ba wọn sọrọ, o lo jẹ iyalẹnu foun nigba toun rii pe wọn n fi otitọ inu ṣe.

Arabinrin Aderonke Margret Diyan ninu ọrọ tiẹ naa sọ pe ninu awọn ọmọọṣẹ wọn lo wa ba oun ni ṣọọbu, toun fi ra idaji pulọọti nigba yẹn lati fi bẹrẹ, to loun tun ti ba wọn dowopọ siwaju sii, nigba toun ri bi nnkan ṣe n lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI