Ọpẹ o! Lẹyin ọjọ marun-un, iyaale ile ti wọn jigbe l'Abẹokuta ti pada sile - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 13, 2023

Ọpẹ o! Lẹyin ọjọ marun-un, iyaale ile ti wọn jigbe l'Abẹokuta ti pada sile


Orin ọpẹ l'awọn ẹbi, ara ati ololufẹ, to fi mọ ọpọ awọn to gbọ nipa bi wọn ṣe ji iyaale ile kan, Arabinrin Adeboye Olubukọnla Arikẹ gbe niluu Abẹokuta mu sẹnu nigba ti wọn gbọ pe awọn to ji obinrin naa gbe ti fi silẹ.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii tii ṣe ọjọ kẹsan, oṣu kinni, ọdun yii ni iroyin fi to wa leti pe wọn ji Arabinrin Arikẹ gbe lagbegbe Gbọnagun, Odo-Ẹran, Ọbantoko.

Wọn ni ọkọ taisi ni obinrin naa wọ lakoko to n lọ sileewe, ṣugbọn ti ko de ileewe ọhun, bẹẹ si ni ko pada sile.


Ọjọ keji ni wọn lo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ wi pe ki awọn eeyan maa ba oun gbadura, nitori pe inu igbo nla kan loun wa pẹlu awọn kan, to si loun ko le sọ pato ibi ti inu igbo naa wa.

AWIKONKO gbọ pe awọn ọlọpaa pada tọpinpin ẹrọ ibanisọrọ obinrin naa de ilu Akurẹ, bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ lẹkunrẹrẹ.


Ni bayii, ninu ọrọ ti ọkọ Arabinrin naa, Ọgbẹni Adeboye fi sita, o jẹ ko di mimọ pe ọkan lara awọn ara adugbo ni wọn kofiri obinrin naa niwaju ile awọn ọmọ alaigbọran to wa lagbegbe Aṣero.

O ni ẹni naa lo gbe e wa sile foun.

Bakan naa, alaga ẹgbẹ AOPSHON nipinlẹ Ogun, Sanusi D.A ninu ọrọ rẹ dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn dide si iṣẹlẹ naa patapata.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI