Ọkọ baluu jabọ lulẹ lojiji, eeyan mejidinlaadọrin (68) gba ọrun lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 16, 2023

Ọkọ baluu jabọ lulẹ lojiji, eeyan mejidinlaadọrin (68) gba ọrun lọ


Ọjọ manigbagbe lọjọ Aiku, Sannde ana, ọjọ kẹẹdogun, oṣu kinni, ọdun 2023 jẹ lorileede Nepal nigba ti ọkọ ofurufu, iyẹn baluu ja lulẹ lojiji, to si mu ẹmi awọn eeyan ti ko din ni mejidinlaadọrin (68) lọ.

Awọn mejilelaadọrin (72) ni iroyin fi to wa leti pe wọn wa ninu ọkọ baluu ọhun lakoko ijamba naa.

Ijamba yii ni wọn lo buru julọ ninu eyi to ti waye lorileede naa laaarin ọgbọn ọdun.

A gbọ pe bi ọkọ baluu naa ṣe ja lati oke, lo ti pin si meji, ti apa kan si wọlẹ lọ, eyi ti apa keji wa loke.

Ọkan lara awọn ọga ọlọpaa lorileede naa, AK Chhetri to ṣalaye ohun to ṣẹlẹ sọ pe wọn ti gbe mọkanlelọgbọn ninu awọn to kagbako ijamba naa lọ si ọsibitu, nigba ti awọn mẹrindinlogoji ṣi wa ninu ilẹ.

Chhetri sọ pe ọọdunrun mita (300-metre gorge) ni inu ilẹ ti apa kan to wọlẹ lọ wa si oke, iyẹn ni agbegbe kan ti wọn pe ni Pokhara, aarin gbungbun Nepal.

Diẹ ree lara awọn fọto ijamba naa:







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI