Kayeefi lọrọ baale ile kan, Ndubisi Wilson Uwadiegwu ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ nipa bo ṣe lu iyawo rẹ, Ogochukwu Anene pa nitori burẹdi to dija silẹ laaarin wọn.
Ọmọ bibi abule Umuokpu to wa niluu Awka, ipinlẹ Anambra ni wọn pe obinrin naa, nigba ti wọn sọ pe ipinlẹ Enugu lọhun ni Ndubisi ti wa.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Anene lo pe ọkọ rẹ lori foonu lati ra burẹdi bọ wa sile, f'awọn ọmọ marun-un ti wọn bi lati jẹun, ṣugbọno ti wọn ni ọkunrin naa loun ko lowo lọwọ.
Loju ẹsẹ ni wọn l'obinrin yii ti lọ wa owo, to si ra burẹdi naa, eyi to ni wọn fẹẹ fi ṣe ounjẹ alẹ.
A gbọ pe bi Ndubisi ṣe wọle nirọlẹ ọjọ naa, yara idana wọn lo gba lọ, to si ba burẹdi naa nibẹ. Wọn ni ko beere bi burẹdi ṣe jẹ, ko to gbe e, to si jẹ gbogbo rẹ tan pata.
Pẹlu ibinu ni wọn sọ pe iyaale ile naa fi lọ koju ọkọ rẹ lati beere idi to fi jẹ burẹdi naa tan, lai ṣẹku f'awọn ọmọ toun ra a fun. Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe ọkunrin naa ti da igbaju-igbamu bo iyawo rẹ.
Nibi ti wọn lo ti n luu ni obinrin naa ti ṣubu lulẹ, to si daku. Ere ni awọn to gbọ si iṣẹlẹ naa kọkọ pe e, afi bi ko ṣe le dide.
Gbogbo akitiyan awọn to wa nibẹ lati ji obinrin naa dide lo ja si pabo, ko to di pe wọn gbe e digbadigba lọ si ọsibitu fun itọju, to si jẹ pe ọsibitu naa ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe obinrin aa ti jade laye.
A gbọ pe iwadii ti n lọ lọwọ.
No comments:
Post a Comment