Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọdun mẹta ati oṣu meje toun n lo lori ipo ko to lati ṣe gbogbo iṣẹ toun ba nilẹ.
Ọmọọba Dapọ Abiọdun lo sọ eyi lonii, ọjọ Aje, Mọnde niluu Odogbolu, ipinlẹ naa, nibi ipolongo idibo ọdun 2023.
Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe pupọ ninu awọn ileri toun ṣe lakoko ipolongo idibo ọdun 2019 loun ti muṣẹ, ati pe iwọnba asiko toun lo, ajakalẹ arun Korona ni ko foun laaye lati ṣe ju bẹẹ lọ.
O ni bi ajakalẹ arun Korona ṣe ja to, oun ko dawọ iṣẹ ṣiṣe duro nipinlẹ Ogun, to si tun ṣeleri wi pe oun yoo ṣe ju atẹyinwa lọ bi wọn ba da oun pada sipo naa lẹẹkeji.
"Inu mi dun pe a wa si Odogbolu lonii, kii ṣe pe a wa bẹbẹ wi pe ki ẹ forijin wa, kii ṣe pe a tun wa n ṣe awọn ileri ti a ko ni le muṣẹ.
"Inu mi dun pe a wa nibi lonii, nitori pe a ti ṣe kọja ohun ti awọn eeyan n reti lati ọwọ wa. Nitori pe ko si ohun to dara fun ipolongo idibo, bi ko ṣe lati ri nnkan sọ.
"Bi awọn akanṣe iṣẹ ti awọn eeyan le fi oju ri, ti wọn le ni imọlara rẹ, ti wọn si tun le fọwọ kan. A ko ri nnkan sọ lọdun 2018. Niṣe la wa n bẹ yin lati dibo fun wa.
"Mo dupẹ pe Ọlọrun gbọ adura wa, O si gbe wa de ilẹ ileri. A ko doju ti yin, gbogbo ileri ti a ṣe naa la n muṣẹ. Ṣugbọn mo fẹ sọ aṣiri kan fun un yin, ọdun mẹta ko to lati ṣe gbogbo nnkan ti a ba nilẹ.
"Koto ti a ba nilẹ ti jinna ju, ṣugbọn diẹdiẹ la n ṣee, awọn eyi ti a si ti ṣe awọn eeyan n rii. O jẹ ki ẹ mọ wi pe ijọba to n ṣe ileri la jẹ nipinlẹ Ogun.
"Emi o le wa sibi lonii, ki n wa maa sọ fun un yin pe gbogbo ẹ la maa ṣe. A ko le ṣe gbogbo ẹ, ṣugbọn awa ko le sọ pe gbogbo ẹ la maa ṣe, ṣugbọn ti a ba sọ fun un yin pe a maa ṣe nnkan, nipa ogo Ọlọrun, a maa ṣee.
"Mo wa fẹ ki ẹ wo ọla ohun ti a ti ṣe laaarin ọdun mẹta ati oṣu meje, ki ẹ fi dibo fun wa. Ọna ti ko din ni irinwo kilomita la ti ṣe. A ṣe ọna si Ijẹbu, Yewa, Ẹgba ati Rẹmọ.
"Odiidi ọdun kan ataabọ ni ajakalẹ arun Korona fi ba wa finra, sibẹ a ko dawọ iṣẹ duro, a ko fi Korona ṣe awawi lati ma ṣiṣẹ. A ṣiṣẹ si ileewe, ọsibitu ati bẹẹ bẹẹ lọ. Fun idi eyi, ẹ dibo fun wa."
No comments:
Post a Comment