Ọdaju abiyamọ! Ẹ wo bi ọkọ atiyawo ṣe lu awọn ọmọ wọn bi ẹran l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 15, 2023

Ọdaju abiyamọ! Ẹ wo bi ọkọ atiyawo ṣe lu awọn ọmọ wọn bi ẹran l'Ekoo


'Ẹ ṣaanu wa, a ko mọ pe bi yoo ti ri ree' lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n jade lẹnu ololufẹ meji kan ti wọn lu awọn ọmọ wọn nilukulu bi ẹran laipẹ yii, nigba ti ọwọ ọlọpaa tẹ wọn.

 
Agbegbe Ẹgbẹda niṣẹlẹ ọhun ti waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Obinrin naa, Busọla Oyediran, to jẹ iya awọn ọmọ naa, ati ọkọ rẹ tuntun, Akebiara Emmanuel, ni ọwọ tẹ lọjọ Ẹti, Furaide to kọja yii.
 
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, sọ fun awọn akọroyin pe ọjọ ori awọn ọmọ naa jẹ ọdun marun-un ati ọdun meji.
 
Iroyin sọ pe awọn alajọgbele tọkọtaya naa, to ri bi wọn ṣe ma n lu awọn ọmọ ọhun, eyi to ti da oriṣiriṣi ọgbẹ si wọn lara, lo fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.
 
Eyi si lo mu ki ọlọpaa fi ofin gbe wọn lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2023.
 
Ajọ to n gbogun ti fifi eeyan ṣe owo ẹru ati iloluko ẹda, NAPTIP, sọ loju opo Twitter rẹ pe tọkọtaya naa ti wa ni atimọle.
 
Bakan naa ni ajọ naa sọ pe wọn o gbe awọn mejeeji lọ sile ẹjọ, lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, 2023.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI