Anita Favour Nwoke ni wọn pe orukọ ọmọbinrin, ọmọ ọdun mejidinlogun naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Wọn ni aarọ kutu ọjọ kẹsan, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii ni Anita dagbere wi pe oun n lọ si ibi iṣẹ oojọ ẹ.
Ilu Ikorodu, ipinlẹ Eko ni wọn sọ pe Anita n gbe, ibẹ naa lo si ti dawati.
Asiko ti wọn lo yẹ ko pada sile, ti wọn ko si rii, eyi lo mu ki wọn wa a lo, ṣugbọn to pada jẹ iyalẹnu fun wọn nigba ti awọn ara ibiṣẹ rẹ sọ pe ko wa lọjọ naa.
Ki ẹnikẹni to ba mọ bi wọn ṣe le rii tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
No comments:
Post a Comment