Ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ Ọṣun, eyi to wa niluu Oṣogbo ti paṣẹ wi pe ki wọn lọ yẹgi fun awọn mẹfa kan, Raṣidi Waidi, Hammẹd Rafiu, Owolabi Bashiru, Kayọde Sunday, Afọlabi Mayọwa, ati Mutiu Azeez, tawọn eeyan tun mọ si Tompolo, lori ẹsun idinjale ati ipaniyan.
Onidajọ Jide Falọla lo gbe idajọ naa kalẹ lonii, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kinni, ọdun 2023.
Mẹrin ninu awọn ọdaran naa, Raṣidi Waidi, ẹni ọdun mọkandinlogoji; Hammẹd Rafiu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji; Owolabi Bashiru, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta ati Kayọde Sunday, toun jẹ ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn ni wọn jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.
Ẹsun mẹfa ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu ipaniyan ni wọn fi kan wọn. Victor Akinbile, to jẹ aburo igbekeji gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Benedict Alabi, ni wọn gbimọ pa lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2018.
A gbọ pe Victor n lọ sibi ayẹyẹ ibura ti wọn ṣe fun Gomina Gboyega Oyetọla ati igbakeji rẹ, Kayọde Alabi lọjọ naa ni, ko to di pe wọn daa lọna niluu Ikirun.
Wọn lawọn mẹrẹẹrin yii ni wọn lọ ka Victor mọ inu otẹẹli rẹ, ti wọn si beere miliọnu mẹwaa naira lọwọ ẹ, igba ti ko ri owo naa ko silẹ fun wọn lo jẹ ki wọn gbe e yin ẹyin mọto rẹ, ti wọn si lọ dana sun un loju ọna Oṣogbo si Ikirun.
A tiẹ gbọ pe Victor fun wọn lowo lọjọ naa, o si tun fi miliọnu mẹta naira ranṣẹ si apo ile ifowopamọ ọkan lara wọn, ko to di pe wọn lọ pa a danu.
Ẹsun meji ti wọn fi kan awọn meji yooku ni idigunjale ati ipaniyan. Wọn ni Afọlabi Mayọwa, ẹni ọdun marundinlogoji ati Mutiu Azeez, iyẹn Tompolo, ẹni ọdun mọkanlelogoji ni wọn pa ọkunrin ọlọkada kan ti wọn sọ pe ko gbe wọn lọ si Ẹgbẹda, ti wọn si tun ji ọkada rẹ gbe salọ.
Yatọ si idajọ naa, Onidajọ Falọla tun paṣẹ pe ko si eyikeyi ninu awọn mẹfẹẹfa to gbọdọ lẹtọọ si idariji ọjọ iwaju lati ọdọ ijọba, nitori pe ohun ti wọn ṣe lagbara kọja idariji.
No comments:
Post a Comment