Ileeṣẹ amofin kan ti wọn pe ni Bidbol Solicitors and Advocates lo ti fi ẹsun iwa idaluru ati gbigbiyanju lati da si ọrọ ọba ti ko kan an kan Balogun ilu Ẹgba, Oloye Sikirulai Atọbatẹlẹ.
Ninu iwe ẹsun naa ti ileeṣẹ amofin ọhun kọ lorukọ Kẹhinde Amusa, Sakirulahi Ọlanrewaju ati Sanmi Ọlatomi, eyi ti wọn kọ ranṣẹ si ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, Department of State Security lọjọ kejila, oṣu kẹsan, ọdun 2022, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ ni wọn ti sọ pe iwa naa le da ogun silẹ laaarin ilu.
Ko si nnkan meji ti wọn lo da wahala yii silẹ, bi ko ṣe ti ọrọ ipo ọba ilu Ijẹja, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe wọn fẹẹ fi ẹnikan ti kii ṣe ọmọ ilu naa, Taiwo Ṣokunbi jẹ olu tiluu Ijẹja, ẹni ti wọn lawọn araalu tako.
Wọn ni iwaati igbesẹ naa le da itajẹ silẹ laarin ilu, fun idi eyi, wọn rọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lati tete da si ọrọ naa, ki wọn si kilọ fun Balogun Ẹgba, Oloye Atọbatẹlẹ, ẹni ti wọn ni kii ṣe ọmọ ilu naa lati da si ọrọ ti ko kan an.
Ọmọ ilu Igbore niluu Abẹokuta ni wọn pe Oloye Atọbatẹlẹ, ti wọn si lo n ṣagbatẹru awọn kan lati gbe Ṣokunbi, ẹni ti kii ṣe ọmọ ilu s'ipo gẹgẹ bi ọba.
A gbọ pe Balogun ilu Ijẹja, Oloye Fẹmi Ṣolankẹ ati Ẹkẹrin ilu Ijẹja, Oloye Yẹmisi Ṣodipọ ni wọn n beere owo to to miliọnu mẹwaa naira lọwọ Ṣokunbi, ninu owo naa ni wọn yoo ti fi ran Balogun Ẹgba, Oloye Sikirulai Ọlatunde Atọbatẹlẹ lati ba wọn ṣiṣẹ naa lọdọ Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Gbadebọ.
Wọn ni latigba naa ni Oloye Atọbatẹlẹ, ẹni to jẹ gẹgẹ bii igbakeji Alake ti n wa ọna alumọkọrọyi, ti Alake yoo fi fọwọ si ẹni ti wọn gba owo lọwọ ẹ, eyi lo wa ninu iwe ẹsun to tẹ AWIKONKO lọwọ.
Wọn ni Ṣokunbi kii ṣe ọmọ ilu Ijẹja, ati pe ẹni ti yoo ba jẹ ọba ilu naa gbọdọ jẹ ojulowo ọmọ ilu, yala lati idile baba tabi iya, ṣugbọn ti wọn ni ko fi ẹbi kan tan mọ ilu Ijẹja, bi ko ṣe pe o wa gbe inu ilu ọhun ni.
Agboole Igbore Ntoji ni wọn sọ pe awọn obi Ṣokunbi ti wa, koda ti wọn sọ pe ekeji Ṣokunbi, iyẹn Ọgbẹni Kẹhinde Ṣokunbi fidi ẹ mulẹ pe awọn kii ṣe ọmọ ilu Ijẹja. Abule Igbore Ẹgba ti wọn n pe ni Seriki-Ṣotayọ, to wa nitosi Ogunmakin, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode, ipinlẹ Ogun ni wọn ti bi awọn mejeeji.
Wọn wa n rọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ati gbogbo awọn ti ọrọ kan, to fi mọ awọn alẹnulọrọ lati ba wọn da si ọrọ naa, ki wọn si da gbogbo awọn to n gbero lati da wahala silẹ niluu Ijẹja lati lọ rọkunle, ki ọrọ ilu Ijẹja ma baa dabi tilu Agodo.
Nigba to n sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan an, Oloye Atọbatẹlẹ sọ pe lotitọ loun kii ṣe ọmọ ilu Ijẹja, ati pe ko si nnkan to kan oun pẹlu ipo ọba to ṣi silẹ niluu Ijẹja.
Oloye Atọbatẹlẹ sọ pe Alake nikan lo le sọrọ lori ẹ, kii ṣe oun Balogun Ẹgba.
Ṣugbọn sibẹ, ohun ti a gbọ ni pe agba oloye naa lo wa lẹyin gbogbo awọn ti wọn fẹẹ fa Ṣokunbi silẹ gẹgẹ bi ọba ilu Ijẹja, ti wọn si lawọn ko nii gba wọn laaye lati jẹ ki ajoji jẹ ọba le wọn lori.
No comments:
Post a Comment