Nnkan daru mọ Chelsea loju nile Man City, apẹrẹ iya ni wọn fi ko goolu lọ sile pẹlu itiju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 8, 2023

Nnkan daru mọ Chelsea loju nile Man City, apẹrẹ iya ni wọn fi ko goolu lọ sile pẹlu itiju


Gbogbo galegale ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lo pada gba itiju nla nigba ti wọn pada agbako nile Manchester City nirọlẹ oni, ọjọ Aiku, Sannde pẹlu aami ayo mẹrin si odo.

Niṣe ni kurukuru bo ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea loju nigba ti nnkan daru mọ wọn loju, to si jẹ pe ika abamọ ni wọn pada mu sẹnu kuro nile Man City.

Orin 'a ti gba yin l'ọga' l'awọn agbabọọlu Chelsea n kọ fun Man City, ti wọn si l'awọn ko tun jẹ foju kere wọn mọ ninu idije FA Cup to waye.

Riyad Mahrez lo kọkọ gbomi loju Chelsea ni iṣẹju mẹtalelogun ti ifigagbaga ọhun bẹrẹ, nigba to gba aami ayo kinni wọle sinu ahọn.
 
Julián Álvarez lo gba aami ayo keji wọle pẹlu pẹnariti ni ọgbọn iṣẹju ti ifigagbaga naa bẹrẹ.

Ere ni wọn pe nigba to ku iṣẹju meje ki saa akọkọ pari, ti Phil Foden si gba aami ayo kẹta wọle s'ahọn Chelsea, eyi to mu k'awọn ololufẹ Chelsea kawọ sori pe awọn ti kagbako nla.

Jinnijinni lo bo ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni ipele keji ifigagbaga naa, ti wọn si n sare kiri ori papa bi ẹni to n wa ẹran okete lati pa.

Bo ṣe ku iṣẹju marun-un ki ifigagbaga ọhun pari ni Chelsea tun ṣiṣe loju ile wọn, ti wọn si fun Man City ni pẹnariti keji. Niṣe l'awọn alatilẹyin Chelsea kaakiri agbaye bu sẹkun nigba ti aami ayo kẹrin wọle sinu ahọn wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI