Njẹ o mọ idi ti ileeṣẹ iwe iroyin Vanguard ṣe fi aami ẹyẹ da AbdulRazaq lọla? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 5, 2023

Njẹ o mọ idi ti ileeṣẹ iwe iroyin Vanguard ṣe fi aami ẹyẹ da AbdulRazaq lọla?


Ileeṣẹ iwe iroyin Vanguard ti kede Gomina Abdurahman AbdulRazaq gẹgẹ bi ọkan lara awọn gomina to ṣe daadaa julọ lorileede Naijiria lọdun 2022.

Kii ṣe pe wọn deedee yan AbdulRazaq mọ awọn gomin to ṣe daadaa naa, bi ko ṣe awọn ipa to n ko ninu eto idagbasoke ipinlẹ Kwara.

Lai sọ asọdun, ilọsiwaju ati idagbasoke alailẹgbẹ ti de ba ipinlẹ Kwara latigba ti AbdulRazaq ti di gomina.

Gbogbo ẹka patapata ni gomina naa ṣiṣẹ de, ti ko si yọ eyikeyi silẹ.

Bo ṣe ṣiṣẹ lẹka eto ẹkọ, lo ṣe lẹka imọ ẹrọ ati ayelujara, to fi mọ awọn ohun amuṣọrọ.

AbdulRazaq ti gba aami ẹyẹ ileeṣẹ iwe iroyin Leadership ati Blueprint.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI