Kaayefi nla lọrọ gendekunrin, akẹkọọ fasiti imọ-ẹrọ tiluu Akurẹ, iyẹn Federal University of Technology, Akure, FUTA ti wọn loo pokunso laipẹ yii ṣi n jẹ fun pupọ awọn ọrẹ rẹ, paapaa awọn to gbọ si iṣẹlẹ ọhun.
Ọlọna Joseph Oluwapẹlumi ni wọn pe orukọ akẹkọọ naa, ẹni ti wọn ni ipele kẹta tii ṣe 300-Level lo wa nile ẹkọ naa, ko to gbẹmi ara rẹ lojiji.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aarọ ọjọ Abamẹta to kọja yii la gbọ pe awọn eeyan ṣakiyesi pe Oluwapẹlumi ti pokunsi sinu yara ile adagbe-akẹkọọ, iyẹn hostel to wa nita fasiti naa.
A gbegbe Aule to wa niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo ni wọn sọ pe ile ọhun wa, iyẹn ile to n gbe.
Ninu atẹjade tiẹgbẹ awọn akẹkọọ fasiti naa gbe jade, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun wọn, ati pe ka ni awọn mọ nipa ipenija ti ọmọkunrin naa n la kọja ni, o ṣee ṣe k'awọn dide iranlọwọ fun un.
A gbọ pe nigba ti awọn ọrẹ Oluwapẹlumi ko gburo rẹ, lo mu ki wọn lọ kan ilẹkun rẹ laaarọ Satide naa, ti wọn ko si gburo rẹ.
Wọn ni kii tilẹkun mọri bẹẹ tẹlẹ, lo mu ki wọn fi agidi ṣi ilẹkun naa wọle, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ba oku rẹ lori oke faanu, to ti gan sibẹ.
Lara awọn to mọ Oluwapẹlumi daadaa ni wọn n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe owo ileewe ati awọn owo to nilo, ti ko tete ri lo fa a to fi gbẹmi ara rẹ lojiji, lai sọ fẹnikẹni.
No comments:
Post a Comment