Aarẹ ana lorileede Naijiria, Goodluck Ebele Jonathan ti sọ pe ọrọ awọn oloṣelu ko yatọ si ọrọ awọonn afọju, nigba ti awọon ba ti wa ni ipo agbara.
Jonathan lo sọrọ naa nibi eto ti wọn fi pari ayẹyẹ ọlọsẹkan ti wọn fi ṣẹyẹ ifẹyinti fun Onidajọ agba ti ipinlẹ Bayelsa, Onidajọ Kate Abiri l'ọjọ Satide, Abatmẹta to kọja.
Nibẹ lo tun ti gba awọn oloṣelu lamọran lati ma ṣe maa ba ẹka eto idajọ jẹ, nitori pe wọn ṣe pataki pupọ ninu idagbasoke orileede.
“Mo rọ awọn oloṣelu wi pe bi wọn ba wa n'ipo agbara, ẹ ma ṣe jẹ ka maa ba orukọ ẹka eto idajọ jẹ, nitori pe wọn w ni ipo to lagbara. Nigba ti a ba gba ipo agbara nidii oṣelu, oju wa maa n di bi afọju. Oloṣelu si gbọdọ mọ pe ile aye yii n yi ni gbogbo igba ni.”
No comments:
Post a Comment