Pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, ko tii daju pe gendekunrin, ọmọ ọdun mejidinlọgbọn kan, Fọlọrunṣhọ Ọlaniyan yoo bọ kuro ninu wahala afọwọfa to fa si ara rẹ lọrun, pẹlu bo ṣe lọ ji jẹnẹretọ kootu.
B'awọn kan ṣe n sọ pe ẹfun ni, bẹẹ lawọn miran n sọ pe eedi ni, ti awọn mi-in si n sọ pe asasi ni.
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii la gbọ pe Ọlaniyan lọ fo fẹnsi wọnu ọgba ile ẹjọ Majisireeti kan n'ipinlẹ Ogun, to si ji jẹnẹretọ ti wọn n lo nibẹ gbe.
Nnkan bi aago meji aabọ ọsan la gbọ pe Ọlaniyan wọnu ọgba kootu naa, to si lọ ja ilẹkun yara ti wọn n tọju jẹnẹretọ naa si, to si jii gbe.
Asiko ti wọn sọ pe isinmi wa f'awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ Ogun lati lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ni wọn sọ pe Ọlaniyan lo anfaani rẹ lati lọ jale naa.
Wọn ni bo ṣe ji jẹnẹretọ ọhun tan, to si fẹ maa salọ ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ kootu naa, Kareem Tolulọpẹ wọle sibẹ, to si kaa mọbẹ.
Niṣe lọrọ womi-n-woẹ nigba ti ọwọ palaba rẹ segi, to si bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ nitori pe iṣẹ eṣu ni.
Ninu ọrọ ti Ọlaniyan sọ, o ni iṣẹ ọkan loun n ṣe tẹlẹ niluu Eko ko to di pe wọn le oun danu, ti wọn si gba ọkada naa lọwọ oun.
O sọ pe latigba naa loun ko ti ri iṣẹ ṣe, ati pe oun tun jẹ gbese owo ile. Owo ile naa lo sọ pe o mu koun lọ ja ilẹkun kootu lati ji jẹnẹretọ wọn gbe, koun si ta a lati fi owo rẹ san owo ile.
Ni bayii, a gbọ pe wọn ti lọ fa a le awọn ọlọpaa Sango lọwọ lati ṣe iwadii rẹ, ko to di pe wọn tun pada foju ẹ ba ile ẹjọ.
No comments:
Post a Comment