Iroyin to tẹ wa lọwọ ti fidi rẹ mulẹ pe Alaaji Musiliu Akinsanya ti awọn eeyan mọ si MC Oluọmọ ti sọ gbajugbaja Ṣeun Ẹgbẹgbẹ di alaga garaaji l'Ekoo.
Oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni iroyin naa jade sita seti gbogbo aye, ti wọn si n ki Ṣeun Ẹgbẹgbẹ ku oriire nla naa.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Ṣeun Ẹgbẹgbẹ jade kuro lẹwọn, lẹyin ọdun marun-un le diẹ to ti wa nibẹ.
Ninu ọrọ ti akọwe MC Oluọmọ, Samuel Ọlatunji kọ sori ikanni ayelujara rẹ laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe Ṣeun Ẹgbẹgbẹ yoo maa ṣakoso garaaji l'Ekoo, ti yoo si maa ri owo nibẹ
Bo tilẹ jẹ pe MC Oluọmọ ati Ṣeun Ẹgbẹgbẹ ti jọ ni aawọ ṣaaju ko to lọ si atimọle.
Atẹjade naa ni MC Oluọmọ yọnda igun awọn Kẹkẹ Maruwa fun Ẹgbẹgbẹ lati jẹ olori wọn.
O ni kii ṣe idunu oun lati ri Ṣeun Ẹgbẹgbẹ pada sinu awọn iwa rẹ atijọ nitori naa ni o ṣe fun un ni iṣẹ lati le rowo jẹun ati lati ṣe itọju obi rẹ.
Dey play now
ReplyDelete