Nibi ti ọrọ de duro bayii, ko tii daju pe ọkunrin ti ọwọ tẹ laipẹ yii yoo bọ ninu wahala afọwọfa to ko ara rẹ si.
Safi Abọlaji, ẹni ti inagijẹ rẹ tun n jẹ Ojulari, ẹni ọdun mẹrinlelogoji la gbọ pe ọwọ tẹ pẹlu ibọn ilewọ meji to ko lọ ibi ipolongo eto idibo t'ẹgbẹ oṣelu APC ṣe lagbegbe Ojuẹkun Sarumi to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọkasanmi Ajayi ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi ranṣẹ s'awọn akọroyin lonii ọjọ Aje, Mọnde, o ni awọn eeyan lo kofiri ibọn lọwọ Ojulari, nibi ipolongo naa to waye lọjọ Aiku, Sannde ana.
Ọkasanmi sọ pe loju ẹsẹ ti wọn ti ka ibọn naa mọ lọwọ ni wọn ti buu so, ti wọn si dana iya fun un, iyẹn ni nnkan bi aago mẹta aabọ ọsan.
Alukoro naa lo jẹ ka mọ pe agbegbe Kankatu ni Ojulari n gbe niluu Ilọrin.
O ni yatọ si ibọn meji ti wọn gba lọwọ ẹ, wọn tun ka ọta ibọn loriṣiriṣi ati oogun abẹnugọngọ mọ-ọn lọwọ.
Nibi ti wọn ti dana iya fun un l'awọn ẹlẹyinju aanu ti dide iranlọwọ fun un, ti wọn si sare ranṣẹ s'awọn ọlọpaa to wa nitosi.
Iwadii pada fidi rẹ mulẹ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti Aye ni Ojulari, ti wọn lo ṣẹṣẹ pari ẹwọn ti wọn ju si ni.
Ko pẹ to jade lẹwọn la gbọ pe o lọ darapọ mọ ipolongo naa lati doju rẹ bolẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa lo tun jẹ ka mọ pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ojulari
Ọkasanmi ni iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lati mọ erongba Ojulari nibi ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu APC, ati idi to fi ko ibọn dani lọ sibẹ, paapaa bi ọwọ yoo ṣe tẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun yooku rẹ.
Bẹẹ lo tun fi ye wa pe ọkunrin yii yoo foju ba ile ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari.
No comments:
Post a Comment