Kasnaty, gbajumọ sọrọsọrọ tun ti dide iranlọwọ fun 'Iya Ibeji Ọmọ Araye Le' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 26, 2023

Kasnaty, gbajumọ sọrọsọrọ tun ti dide iranlọwọ fun 'Iya Ibeji Ọmọ Araye Le'


Kaakiri agbaye l'awọn ololufẹ gbajugbaja oṣere tiata nni, Arabinrin Adenikẹ Adegboye, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si 'Iya Ibeji Ọmọ Araye Le' ti n ṣe adura fun ilu-mọ-ọn-ka sọrọṣorọ agbaye nni, Kọlawọle Atanda Adejojo lori iranlọwọ to tun n ṣe fun mama naa.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ileeṣẹ iroyin BBC YORUBA lọ ṣe ifọrọwerọ fun Iya Ibeji Ọmọ Araye Le to wa lori idubulẹ aisan, nibi ti ọmọ rẹ to duro ti, ti ṣalaye pe awọn nilo iranlọwọ.

Ifọrọwerọ naa lo lọ kaakiri ori ikanni ayelujara lọsẹ to kọja yii.


Lara awọn iranlọwọ ti wọn ni mama naa nilo bayii ni ti ile ti yoo maa gbe, paapaa eyi ti wọn yoo ti raaye tọju ẹ daadaa, ki ara rẹ le ya.

AWIKONKO gbọ pe owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati ọgọta (N360,000) naira lowo to ti wa nilẹ bayii, ti awọn eeyan ti da lati fi ran Iya Ibeji lọwọ. 
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI