Ipolongo idibo 2023: Tinubu gbarada niluu Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 17, 2023

Ipolongo idibo 2023: Tinubu gbarada niluu Ilọrin


Ilu Ilọrin nipinlẹ Kwara lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee mọ pe awọn gbalejo nla, koda, ti wọn ni iru ero bẹẹ ko wọ ipinlẹ naa ri latigba ti wọn ti da wọn silẹ.
 
Ẹsẹ ko gbero rara niluu Ilọrin nigba ti ikọ oludije s'ipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima balẹ gudẹ sibẹ lati polongo ibo.

Bi wọn ṣe wọlẹ pẹlu ikọ igbimọ ipolongo naa ni wọn lawọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ wọn ti lọ pada wọn, lati ki wọn kaabọ.
 
Lara awọn ti wọn kọwọrin ni alaga ẹgbẹ APC lapapọ, Abdullahi Adamu, ti Alaaji Lai Mohammed, to jẹ minisita fọrọ eto iroyin ati irin ajo afẹ lorileede yii si wa lara awọn to lọ pade wọn.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI