Ile-ẹjọ wọgile ẹsun ti PDP fi kan AbdulRazaq ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 13, 2023

Ile-ẹjọ wọgile ẹsun ti PDP fi kan AbdulRazaq ni Kwara


Ile ẹjọ giga apapọ to fikalẹ siluu Abuja ti paṣẹ pe oun wọgile ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ẹka t'ipinlẹ Kwara pe lati tako ipadasipo gomina AbdulRaham AbdulRazaq lẹẹkeji.
 
O ni ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ rara, fun idi eyi, o wọgi lee.
 
Ẹgbẹ oṣelu PDD la gbọ pe wọn pe ẹjọ naa, nibi ti wọn ti n rọ ile ẹjọ lati paṣẹ pe ki ajọ eleto idibo yọ orukọ AbdulRazaq kuro ninu awọn ti yoo dije nibi eto idibo ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ, Onidajọ Inyang Ekwo sọ pe ẹsun naa ko kun to, ati pe o tapa si ọna ti wọn n gba gbe ẹjọ wa siwaju adajọ.

Bakan naa lo sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni aṣẹ tabi ẹtọ yoowu lati pe ẹjọ tako oludije lẹgbẹ miran, niwọn igba ti kii ṣe inu ẹgbẹ wọn ni wọn ti ṣeto idibo abẹle.
 
Lara awọn ẹsun ti PDP fi kan AbdulRazaq lọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ ni pe ayederu iwe ẹri ti ile ẹkọ girama lo ko kalẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ati ajọ INEC.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI