Ile ẹjọ da ẹsun ti wọn pe lati yọ Buhari danu gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria nu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 30, 2023

Ile ẹjọ da ẹsun ti wọn pe lati yọ Buhari danu gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria nu


Ile-ẹjọ giga lorileede yii to wa niluu Abuja ti da ẹsun ẹsunn wi pe ki wọn yọ Aarẹ Muhammadu Buhari n'ipo gẹgẹ bi aarẹ orileede Naijiria nu, to si ni ko lẹsẹ nilẹ rara.
 
Oludije s'ipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Hope Democratic Party, Oloye Ambrose Owuru lo pe ẹjọ naa wi pe oun fẹ ki ile ẹjọ naa kede oun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo ọdun 2019.
 
Ẹsun naa ni Onidajọ Inyang Ekwo danu lori idi mẹta pataki, eyi to sọ pe o bu ẹnu atẹ lu ile-ẹjọ lonii, ọjọ Aje, Mọnde.
 
Bakan naa ni Onidajọ Ekwo tun sọ pe ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ rara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI