Ikunlẹ abiyamọ o! Ṣọọṣi ni iyaale ile nlọ ko to kagbako iku ojiji l'Abẹokuta lọjọ Aiku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 9, 2023

Ikunlẹ abiyamọ o! Ṣọọṣi ni iyaale ile nlọ ko to kagbako iku ojiji l'Abẹokuta lọjọ Aiku


Ariwo Ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Ọbantoko to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun nibi ti iyaale ile kan ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Nnkan bi aago mẹsan kọja iṣẹju mẹwàá la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye niwaju ile epo Mobil to wa ni Fajol, loju ọna Abẹokuta si Ibadan.

AWIKONKO gbọ pe ṣọọṣi ni iyaale ile naa ati ọkọ rẹ, to fi mọ ọmọ rẹ n lọ laaarọ ọjọ naa, ko to di pe wọn kagbako ijamba naa.

Lara awọn to wa nibẹ lo jẹ ko ye wa pe ọkọ arabinrin naa lo gun ọkada naa, ko to di pe ọlọkada miran lọ kọlu wọn.

Wọn ni kete ti ọlọkada naa ti rii pe eeyan ti ku ninu ijamba ọhun lo ti na papa bora, ti wọn ko si rii mu.

Agbẹnusọ fun ajọ ẹṣọ oju popona nipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe oju ẹsẹ ni obinrin naa ti ku, ti ọkọ ati ọmọ rẹ farapa yannayanna.

Akinbiyi lo jẹ ka mọ pe nọmba idanimọ TTN 08 VG lo wa lara ọkada yii, to si gba awọn ọlọkada lamọran lati maa ṣe jẹjẹ lori ọkada wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI